Ọwọ tẹ awọn Fulani ti wọn n ji awọn eeyan gbe l’Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn afurasi meje lọwọ ẹsọ Amọtẹkun ipinlẹ Ondo ti tẹ latari ijinigbe to n waye lemọlemọ loju ọna marosẹ Ọwọ si Akungba Akoko.

Awọn ajinigbe ọhun, Muhammed Umaru, Suleiman Aliu, Abubakar Ibrahim, Abudu Barzor, Muhammed Tukur, Aota Bello ati Cindu Yahu lọwọ palaba wọn ṣegi lẹyin ti wọn ji oloye adugbo kan niluu Ikarẹ Akoko atawọn mẹrin mi-in gbe lagbegbe Agọ Paanu, lagbegbe Ọwọ, lọsẹ meji sẹyin.

 

Awọn afurasi ọhun la gbọ pe wọn tun ji awọn mẹta mi-in gbe lagbegbe yii kan naa, ti wọn si yinbọn pa ẹnikan nibi to ti n gbiyanju ati sa mọ wọn lọwọ.

Awọn tọwọ ba naa nijọba ipinlẹ Ondo ti wọ lọ sile-ẹjọ Majisreeti kan niluu Akurẹ, lori ẹsun mẹrin ọtọọtọ ti wọn fi kan wọn.

Lara ẹsun ti wọn fi kan awọn janduku agbebọn ọhun lasiko igbẹjọ ni jiji awọn arinrin-ajo mẹta, Bello Mukaila, Niran Adeyẹmọ ati Risikatu Suleiman gbe lọjọ kẹrin, oṣu ta a wa yii, ti wọn si tun yinbọn pa ẹnikan ti orukọ rẹ n jẹ Mudasiru, nigba to fẹẹ sa lọ mọ wọn lọwọ.

Wọn lawọn olujẹjọ ọhun tun digun ja ọkunrin kan ti wọn n pe ni Abdul Murtala lole, ti wọn si fipa gba owo to to bii miliọnu mẹrin lọwọ rẹ.

Awọn ẹsun ọhun ni wọn lo ta ko iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006, ati ofin orilẹ-ede Naijiria ti ọdun 2004, eyi to lodi si idigunjale, ijinigbe ati siṣe amulo nnkan ija oloro lọna ti ko bofin mu.

Agbefọba ni oun dabaa ki wọn fi awọn afurasi naa pamọ si ọgba ẹwọn na, ṣugbọn agbẹjọro awọn olujẹjọ, Ọgbẹni U. F. Salau, ta ko aba yii, o ni oun rọ adajọ ko fun oun laaye lati fesi lori gbogbo aba ti agbẹnusọ fun ijọba fi siwaju ile-ẹjọ.

 

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Damilọla Ṣekoni ni oun paṣẹ ki wọn da awọn afurasi naa pada sọdọ awọn ẹsọ. Amọtẹkun titi di ọjọ kejidinlogun, oṣu yii.

Leave a Reply