Wọn ti wọ Jacob at’ọrẹ ẹ to n ṣẹgbẹ okunkun l’Ọrẹ lọ sile-ẹjọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun meji tọwọ tẹ niluu Okitipupa lọsẹ to kọja yii, Israel Jacob ati Akinbomi Ayọọla, ni wọn ti wọ lọ sile-ẹjọ Majisreeti Oke-Ẹda, l’Akurẹ, lori ẹsun gbigbimọ-pọ huwa to ta ko ofin, siṣe amulo nnkan ija oloro lọna aitọ, ẹgbẹ okunkun ṣiṣe ati didun ikooko mọ ẹmi ẹni.

Ni ibamu pẹlu alaye ti Agbefọba, Abdulateef Suleiman, ṣe lasiko tawọn afurasi mejeeji n fara han nile-ẹjọ, o ni ọjọ kejilelogun, oṣu Keje, ọdun yii lọwọ tẹ awọn mejeeji niluu Ọrẹ, nijọba ibilẹ Odigbo.

O ni yatọ si ibọn ti awọn agbofinro ka mọ awọn olujẹjọ naa lọwọ lọjọ naa, o ni ṣe ni wọn tun n halẹ mọ ẹnikan ti wọn porukọ rẹ ni Ayọdele Ojuetimi, pe awọn fẹẹ dana sun ile rẹ.

Ẹsun mẹrin ti wọn ka si awọn olujẹjọ naa lẹsẹ lo ni o ta ko abala kọkandinlogun ati okoolelẹẹẹdẹgbẹta din ẹyọ kan ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Agbefọba ọhun bẹbẹ fun sisun igbẹjọ siwaju ko le lanfaani lati fi awọn iwe ẹjọ naa ṣọwọ si ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Onidaajọ Tọpẹ Aladejana gba ẹbẹ agbẹnusọ fun ijọba wọle pẹlu bo ṣe ni kawọn olujẹjọ ọhun ṣi lọọ maa ṣe faaji na ninu ọgba ẹwọn Olokuta.

Adajọ ọhun paṣẹ fun awọn ọlọpaa lati tete fi awọn iwe to ni i ṣe pẹlu ẹsun wọn ṣọwọ si ọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran kiakia, bẹẹ lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kọkanla, osu Kẹsan-an, ọdun 2022.

Leave a Reply