Ere itiju ni ẹgbẹ APC yoo gba pada bọ nile-ẹjọ ti wọn gbe mi lọ-Adeleke

Gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ọṣun, Sẹnetọ Ademọla Adeleke, lọjọ Abamẹta, Satide, to lọ yii, lo ni ere ẹtẹ lawọn APC n ṣe, ere itiju ni wọn yoo si gba pẹlu ile-ẹjọ ti wọn gba lọ pe oun kọ loun jawe olubori ninu ibo gomina ti wọn di nipinlẹ naa lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, nitori ibo to lọ nirọwọ rọsẹ lai mu wahala tabi magomago kankan dani bo ti wu ko mọ ni.

Niluu Ijẹbu-Jẹṣa, nipinlẹ Ọṣun, ni Adeleke ti sọrọ ọhun lasiko to n gbalejo kọmiṣanna fun eto iṣuna tẹlẹri lasiko iṣejọba Rauf Arẹgbẹṣọla, Dokita Wale Bọlọrunduro, atawọn alatilẹyin rẹ ti wọn ṣẹṣẹ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP lakooko ti wọn n ṣe iwọde ni ilu naa.

O loun to jẹ oun logun ju bayii ni ọna lati mu itẹsiwaju ba ipinlẹ Ọṣun, bẹẹ lo tun ṣeleri pe ohun yoo sa ipa oun lati ko ipa pataki ti yoo mu ayipada nla ba ipinlẹ Ọṣun laarin ọgọrun-un ọjọ toun ba de ọọfiisi.

“Gbogbo agbaye lo mọ pe eto idibo ọhun lọ nirọwọ rọsẹ. Awọn ẹgbẹ oṣelu APC kan n daamu ara wọn ni, ifakokoṣofo ni mo si ri i si. Loootọ ni wọn lẹtọọ lati lọ si kootu o, ṣugbọn ofo ni wọn maa ba bọ nibẹ.

Ki awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ti wọn fibo gbe wa wọle fọkan balẹ, ki wọn ma si ṣe mikan. Lọtẹ yii o, awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ti sọrọ, ero Ọlọrun si ni.

Nnkan to mumu laya mi ju bayii ni bi mo ṣe fẹẹ gbe ipinlẹ Ọṣun goke agba, mo si n ṣeleri pe ki n too lo ọgọrun-un ọjọ ni ọọfiisi, iyipada ara ọtun yoo ba ipinlẹ yii”.

Nigba to n ba awọn ti wọn n ṣewọde sọrọ, Bọlọrunduro ni oun atawọn alatilẹyin oun waa darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP nitori pe ẹgbẹ Alaburanda gangan ni ẹgbẹ onitẹsiwaju.

Bọlọrunduro to ṣiṣẹ pọ pẹlu Arẹgbẹṣọla ni saa akọkọ rẹ ni, “Emi ati awọn ọmọ ẹyin mi n darapọ mọ ẹgbẹ PDP lonii ọjọ Abamẹta, Satide, nitori pe oun lẹgbẹ awọn onitẹsiwaju. Ẹgbẹ to fara han ti ko ni kọnu-n-kọhọ tabi iwa ẹtan ninu yatọ si ẹgbẹ ti mo wa tẹlẹ.

“Mo fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ nitori pe wọn n dọwọ bo ogo gbogbo ọna ti mo n gba kopa ninu ẹgbẹ naa. Ẹgbẹ Onigbaalẹ kun fun ẹtan ati irẹnijẹ, ko si ohun ti a le maa pe ni itẹsiwaju ninu ẹgbẹ ti wọn n pe lẹgbẹ onitẹsiwaju ọhun”.

Nigba to n fesi si ọrọ Adeleke, oluranlọwọ pataki lori eto iroyin si alaga ẹgbẹ APC nipinlẹ Ọṣun, Kọla Ọlabisi, ni ki wọn ma ṣe da ẹni ti wọn kede gẹgẹ bii gomina tuntun ọhun lohun, o fi kun un pe oun o ni aroye kankan lati ṣe ki awọn too dele-ẹjọ, koun ma baa tibi ọrọ koba ara awọn nilẹ-ẹjọ.

 

 

Leave a Reply