Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
O kere tan, eeyan meje lo ti padanu ẹmi wọn, ti ọpọ dukia si ṣegbe, latari arọọda ojo to waye niluu Patigi, to wa nijọba ibilẹ Patigi, nipinlẹ Kwara.
Adari ajọ kan ti wọn n pe ni Hydroelectric Power Producing Areas Development Commission (HYPPADEC), Alaaji Abubakar Yelwa, lo sọ eleyii di mimọ fun awọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, niluu Patigi, lasiko to n ṣe ifilọlẹ eroja iranwọ to to aadọta miliọnu Naira (50m), fun awọn to lugbadi nibi iṣẹlẹ naa. O ni ẹgbẹrun kan le ni ọọdunrun ile (1, 300), ni agbara ojo ṣe lọṣẹ, eeyan ẹgbẹrun mẹta din igba (2,800), lo fara kaasa, ti omi si tun gbe ọpọlọpọ ere oko lọ niluu Patigi.
Lara awọn eroja ti wọn pin fun awọn to fara kaasa ni bẹẹdi, irẹsi, awọn ọṣẹ ifọsọ, ọṣẹ iwẹ ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Yelwa, waa rọ gbogbo awọn to n gbe ni bebe odo ki wọn tete ko aasa wọn tefe-tefe kuro ni eti odo bayii lati dena irufẹ iṣẹlẹ bẹẹ lọjọ iwaju, tori pe agbara ojo to lagbara gidigidi ṣi n bọ, ti ijọba apapọ si le ma ni agbara lati tẹsiwaju lati ṣe iranwọ fun wọn mọ. O fi kun un pe HYPPADEC, ti fẹẹ ṣe agbatẹru ofin ti yoo fi kun iye kilomita ti awọn eeyan gbọdọ fi takete si odo nigba ti wọn ba fẹẹ kọle lati dena pipadanu ẹmi ati dukia sọwọ odo.