Baba atọmọ pa Gbenga, wọn kun ẹya ara ẹ si wẹwẹ l’Akurẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Lori ẹsun siṣeku pa Gbenga Abiọla, ti wọn si tun ko ẹya ara rẹ pamọ, baba ẹni ọgọta ọdun kan, Alagba Oṣuọlale Falọwọ ati ọmọ rẹ, Ọlaolu Falọwọ, ẹni ogun ọdun, ti n kawọ pọnyin rojọ nile-ẹjọ Majisireeti to wa l’Akurẹ.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ yii waye labule kan ti wọn n pe ni Kuṣeru, nijọba ibilẹ Odigbo, ninu oṣu Kẹjọ, ọdun ta a wa yii.

Ninu alaye ti Ripẹtọ Suleiman Adebayọ ṣe lasiko tawọn afurasi ọdaran mejeeji n fara han nile-ẹjọ, o ni Ọlaolu fẹnu ara rẹ jẹwọ fawọn agbofinro nigba ti wọn n fọrọ wa a lẹnu wo pe loootọ loun pa ọkunrin ẹni ọdun mẹẹẹdọgbọn ọhun lọjọ iṣẹlẹ ọhun.

O sọ ninu akọsilẹ rẹ ni tesan pe asiko ti oun lọ sinu igbo kan to wa nitosi abule awọn loun ri Gbenga nibi to sun si, to n sinmi.

Bi Oloogbe ọhun ṣe ri i to yọ lọọọkan lo bẹrẹ si i bẹ ẹ lati waa ran oun lọwọ, ṣugbọn dipo ti iba fi ran ọkunrin to ti rẹ naa lọwọ, ṣe lo fa ada yọ, to si kuku ran ẹni ẹlẹni sọrun aremabọ, lẹyin eyi lo tun kun un bii ẹni kun ẹran, to si ko ẹya ara rẹ sinu apo, eyi to lọọ gbe pamọ sile baba rẹ.

Nigba ti oorun buruku to n jade lati inu ile wọn fẹẹ di awọn aladuugbo wọn nimu ni wọn lọọ ba awọn olori abule ọhun lati fi ohun ti wọn ṣakiyesi to wọn leti.

Awọn olori ti wọn lọọ fọrọ lọ foju ara wọn ri ẹru tawọn afurasi ọhun gbe pamọ sile, ni wọn ba sare lọọ fẹjọ awọn mejeeji sun ni teṣan ọlọpaa.

Lara awọn ẹsun ti wọn ka si wọn lẹsẹ ni gbigbimọpọ lati paayan, fifi ọwọ kan oku ẹni ẹlẹni lọna aitọ, biba ori, ẹsẹ ati apa ẹnikan ti wọn n pe ni Gbenga Abiọla ni ikawọ wọn, ti wọn ko si ri alaye gidi kan ṣe lori ọrọ naa.

Awọn ẹsun ọhun ni agbefọba juwe gẹgẹ bii eyi to lodi, to si tun ni ijiya to lagbara labẹ ofin ipinlẹ Ondo ti ọdun 2006.

Agbẹnusọ ọhun rọ ile-ẹjọ lati paṣẹ fifi awọn olujẹjọ mejeeji si ọgba ẹwọn titi ti wọn yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to gba adajọ nimọran.

Amofin Joseph Arinju to jẹ agbẹjọro fawọn olujẹjọ ko ta ko aba ọhun.

Onidaajọ Temitayọ Owolabi gba ẹbẹ agbefọba wọle pẹlu bo ṣe ṣe ni ki wọn lọọ fi baba ati ọmọ naa pamọ si ọgba ẹwọn Olokuta titi di ọjọ kẹwaa, oṣu kẹwaa, ọdun 2022.

Leave a Reply