Alaga ijọba ibilẹ Ido lu lọọya lalubami n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Lẹyin oṣu kan aabọ ti wọn da alaga kansu Ido, nipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Sherif Adeọjọ, duro nitori iwa ibajẹ, wọn lọkunrin naa tun ti huwa ibajẹ mi-in pẹlu bo ṣe lu lọọya kan bii ẹni maa pa a.

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹsan-an, ọdun 2022 yii, lalaga kansu to wa lẹnu idaduro yii lu gbajumọ agbẹjọro kan n’Ibadan, Amofin Tolu Fowode, nilukulu nileetura kan ti wọn n pe ni 530 Lounge, laduugbo Oluyọle.

Wọn ni ọrọ ti ko to nnkan rara l’Ọnarebu Adeọjọ, ọkan ninu awọn ọmọ bibi inu Alhaji Yekini Adeọjọ, agba ọjẹ oloṣelu ọmọ ẹgbẹ PDP nilẹ yii, sọ dija mọ agbẹjọro naa lọwọ, to si bẹrẹ si i rọjo ikuuku le onitọhun lori.

Ẹnikan tiṣẹlẹ ọhun ṣoju ẹ royin pe “Aaye igbalejo awọn eeyan pataki nileetura yẹn la wa nigba yẹn ta a ti n sọrọ, bi Adeọjọ ṣe sọ ọrọ ti ko to nnkan di ibinu mọ Lọọya Toku lọwọ niyẹn. Nigba ta a fi maa mọ nnkan to n ṣẹlẹ, o ti bẹrẹ si i ko ikuuku bo wọn.

“Bi awa ta a wa nibẹ ṣe n mu un lo tubọ n ran eegun apa si lọọya. Koda, nibi to ka a lara de, o tun n wa igo kiri lati gun agbẹjọro naa, bo tilẹ jẹ pe o ti muti yo lọjọ yẹn”.

Awọn oṣiṣẹ ileetura ohun la gbọ pe wọn gba agbẹjọro naa lọwọ alaga ọmọ ẹgbẹ PDP ijọba ibiilẹ Ido yii, wọn si fi aidunnu wọn han nipa iṣẹlẹ yii.

Ninu atẹjade ti ọkan ninu awọn alakooso ileetura yii, Ọgbẹni Ṣeyi Adewale, fi sita, wọn tọrọ aforiji lọwọ awọn onibaara wọn to wa nibẹ lasiko iṣẹlẹ ọhun, bẹẹ ni wọn bẹ Amofin Fowode lati fọwọ wọnu lori iya iwọsi ti alaga kansu naa fi je ẹ.

Bo tilẹ jẹ pe akọroyin wa ko ri Adeọjọ ba sọrọ, ohun tọkunrin naa sọ fawọn to ba a sọrọ ni pe ọrọ ko ri bẹẹ, o ni awọn to n gbe iroyin naa kaakiri kan n lo o lati ba oun lorukọ jẹ ni.

 

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 yii, lawọn kansilọ kansu ọhun kede idaduro alaga naa.

Oriṣiiriṣii ẹsun ni wọn ka si Adeọjọ lẹsẹ, wọn lọkunrin naa ko ni akoyawọ, bẹẹ nijọba rẹ ko ṣiṣẹ idagbasoke ilu to bo ṣe yẹ.

Leave a Reply