Eedi ree o, Daniel gun ọrẹ ẹ pa nitori ounjẹ

Monisọla Saka

Ọmọdekunrin kan, Daniel Akindele, ti dero atimọle bayii lẹyin ti wọn fẹsun kan an pe o ṣeku pa ọrẹ ẹ, Ayọ Bameke, lagbegbe Abbattoir Complex, Agege, nipinlẹ Eko, nitori ounjẹ.

ALAROYE gbọ pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti Akindele ati Bameke pẹlu awọn ọrẹ wọn to ku maa lọ si complex lati lọọ gba bọọlu, ibi ti wọn maa n lọ ni gbogbo igba ni. Amọ lọjọ ti iṣẹlẹ buburu yii maa ṣẹlẹ, gbara ti wọn de ibi ti wọn ti maa n gba bọọlu ni Bameke sọ fawọn ọrẹ ẹ pe oun fẹẹ lọọ wa ounjẹ ra.

Bo ṣe pada de si complex loun ti ki ounjẹ mọlẹ ni tiẹ to n jẹun lọ gẹgẹ bi akọroyin Punch ṣe ṣalaye. Akindele ti ebi ti n pa tẹlẹtẹlẹ naa ba sun mọ ọn, o ni ko jẹ kawọn jọ jẹ ẹ. Ọrọ fun-mi-jẹ mi-o-fun ẹ jẹ yii lo di ariyanjiyan to pada dija laarin awọn ọrẹ mejeeji ọhun.

Lasiko ti wọn n ja lọwọ niwaju odo ẹran Harmony Abbattoir Management Services Limited, ni Bameke to ti doloogbe yii ti ki sisọọsi mọlẹ, to fi ṣe Akindele leṣe, nitori pe iyẹn fẹẹ jẹ ounjẹ ẹ lagidi.

Gẹgẹ bi alaye ti Ọgbẹni Ṣẹgun Ijaọla to n ṣiṣẹ ọlọdẹ nileeṣẹ tawọn ọmọ yẹn n ja niwaju ẹ ṣe fawọn oniroyin, o ni bi Bameke ṣe fi sisọọsi ya Akindele lọwọ tan ni Akindele raga bo o nitori apa ẹ ka ọmọ tọhun, o si ṣe bẹẹ fi sisọọsi ọhun gun Bameke laya titi tẹmii fi bọ lara ẹ.

O ni, “Mẹrin lawọn ọmọ yẹn, ọjọ ori wọn maa wa laarin ọmọ ọdun mẹrinla si mẹẹẹdogun, wọn dẹ jọ maa n wa papọ ni gbogbo igba ni. Ṣugbọn ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Abamẹta, Satide, yẹn, iwaju Abbattoir ni wọn wa. Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ wa lobinrin lo jade sita ninu odo ẹran to fẹẹ lọọ ra nnkan nigba to ri i ti Bameke sun silẹ nibẹ gbalaja lai minra.

Gẹgẹ bi agbalagba, obinrin yẹn rin sun mọ wọn diẹ lati beere ohun to n ṣẹlẹ, lo ba ṣẹwọ si awọn mẹta to ku pe ki wọn sun mọ oun. Nibẹ ni wọn ti ri i pe lapa osi igbaaya ni wọn ti gun Bameke pẹlu sisọọsi ti wọn maa n lo ni ọsibitu. Bi Akindele ṣe ri i pe o daa bii pe Bameke o mi mọ lo fẹẹ sa lọ, ṣugbọn obinrin yẹn tete gba a mu.

“Lasiko ti wọn beere bọrọ ṣe jẹ lọwọ ẹ, Akindele jẹwọ pe Bameke lo kọkọ fi sisọọsi ge oun lọwọ, koun naa too gun toun pada lapa osi igbaaya ẹ.

‘‘Loju-ẹsẹ lawọn oṣiṣẹ ileeṣẹ wa sare gbe Bameke digbadigba lọ sile iwosan Merit Hospital, Agege, ṣugbọn awọn dokita sọ pe ọmọ naa ti dakẹ. Wọn ti pada gbe oku ẹ lọ sile igbokuu-pamọ-si”.

Awọn agbofinro ti wọn wa lagbegbe Abbattoir ni wọn fi panpẹ ofin gbe awọn ọrẹ mẹta yooku, amọ lasiko ti wọn n ṣewadii ni wọn da awọn meji to ku silẹ lẹyin ti wọn ti ri okodoro ọrọ pe wọn o mọwọ mẹsẹ ninu ọrọ naa, loju-ẹsẹ ni wọn ti ju Akindele sẹyin kanta, ki wọn too pada taari ẹjọ naa lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ṣewadii iwa ọdaran ni Panti, Yaba, nipinlẹ Eko.

Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundenyin, to fidi ọrọ naa mulẹ ṣalaye pe adajọ kootu Majisireeti Yaba fẹsun ipaniyan kan Akindele lọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, o si pa a laṣẹ pe ki wọn sọ ọmọkunrin naa satimọle.

Leave a Reply