Faith Adebọla
Nibikibi ti olori orileede wa tẹlẹri, Oloye Oluṣẹgun Arẹmu Okikiọla Ọbasanjọ, ba wa lasiko yii, ṣinkin ni inu rẹ yoo maa dun, ori rẹ yoo si wu, bo ba gbọ nipa amọran gidi kan ti igbakeji rẹ tti wọn jọ ṣejọba, Atiku Abubakar, gba Aarẹ Muhammadu Buhari ati ijọba rẹ. Ọkunrin naa sọ pe ki wọn forukọ ati fọto ọga oun atijọ naa sara ọkan ninu awọn owo Naira ti wọn fẹẹ paarọ awọ rẹ laipẹ, o ni nnkan iwuri lo maa jẹ fun awọn iran to n bọ lorileede yii lati wo awokọṣe Ọbasanjọ, tori ko si meji igi obi nigbo, o leeyan amuyangan, aṣaaju takun-takun l’Ẹbọra Owu i ṣe, gẹgẹ bawọn eeyan kan ṣe n pe e.
Atiku sọrọ yii lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karun-un, oṣu Kọkanla yii, nigba to n kan saara si Ọbasanjọ fun bo ṣe ṣeto ipade alaafia laarin awọn alagbara aye meji ti wọn ki i rimi ara wọn laatan fọjọ pipẹ, iyẹn ijọba orileede Ethiopia ati ẹgbẹ oṣelu Tigray, ti baba naa si pari ija wọn nitubi-inubi, tawọn alaṣẹ mejeeji fi gba lati jogun-o-mi, ti wọn tun di mọra wọn.
O ti le ni ọdun meji sẹyin ti ẹgbẹ oṣelu Tigray Peoples Liberation Front ti wa a ko pẹlu orileede Ethiopia, ti ina ija ogun abẹle si n gbona girigiri niha Ariwa orileede ọhun. Ọpọ ẹmi to ju ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un lọ lo ti ba ogun buruku ọhun rin.
Ṣugbọn laipẹ yii, ti ajọ Iṣọkan ile Adulawọ, iyẹn Africa Union, yan Ọbasanjọ lati ṣaaju ikọ apẹtu-saawọ kan, lati wa ojuutu si lọgbọlọgbọ naa.
Lẹyin ọjọ diẹ ti Ọbasanjọ wọle ijiroro pẹlu ijọba Ethiopia atawọn ẹya to fẹẹ ya lọ naa ni wọn gba lati sinmi agbaja, ti tọtun-tosi wọn si di mọra wọn, ti wọn ya fọto pẹlu Ọbasanjọ, ti wọn si n rẹrin-in alaafia, bo ṣe wa ninu fotọ ati fidio ti wọn gbe jade lẹyin naa.
Ninu ọrọ iwuri ti Atiku gbe sori ikanni tuita (twitter) rẹ, ọ kọ ọ bayii pe:
“Inu mi dun gidigidi, mo si n yayọ iwa akinkanju ati aapọn ọlọla ju lọ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, lati da alaafia pada sorileede Ethiopia. Ko ya mi lẹnu o. Mo mọ ọga mi daadaa bii ẹni m’owo. Bo ṣe ṣe lorileede Liberia ati Sao Tome and Principe niyẹn nigba ta a fi jọ wa lori aleefa. Ta o ba tiẹ ro awọn nnkan mi-in, Ọbasanjọ to, o si yẹ, lẹni ti wọn n fi ẹbun Oluwa Alaafia agbaye (Nobel Peace Prize) da lọla, ma a darukọ ẹ mọ awọn ti wọn maa fun lẹbun naa tasiko ba to.
“Ilẹ Africa ṣoriire lati ni iru agba ọjẹ onṣejọba bii Oloye Ọbasanjọ to fẹran eto ijọba awa-ara-wa daadaa, ọkunrin to yẹ ki orukọ ati aworan rẹ wa lara owo Naira ilẹ wa ti wọn fẹẹ tun pa laro bayii ni, lati le fun awọn iran to n bọ ni iṣiri pe ki wọn lẹmi-in ifara-ẹni-rubọ ati ifẹ orileede ẹni, ati ilẹ adulawọ bii tiẹ. Mo rọ ijọba Buhari lati gba eyi yẹwo.
Lorukọ emi ati idile mi, mo ki ọ kuu oriire o, aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ, GCFR. Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun laakaye, ọgbọn ati ọgbọn-inu to fun ẹ, eyi to o n lo lati tukọ Naijiria ati ilẹ Afrika sọna to tọ.”
Yatọ si Atiku, oludije funpo aarẹ lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, naa ti gboṣuba sadankata fun Ọbasanjọ, bẹẹ lawọn alaṣẹ orileede ilẹ Africa kan, titi kan ajọ Iṣọkan Agbaye, United Nations, atawọn ọtọkulu kari aye ni wọn n kan saara si i, wọn eegun bii eyin ṣọwọn loootọ, ẹni amuyangan gidi ni baba arugbo naa i ṣe.