Awọn ọlọpaa sọ pe loootọ ni, omi lọmọ Davido mu ku  

Adewumi Adegoke

Abajade iwadii tawọn ọlọpaa ṣe lori iku ọmọ ọkan lara awọn olorin taka-sufee ilẹ wa, David Adeleke ti gboggbo eeyan mọ si Davido ti fidi rẹ mulẹ pe niṣe ni Ifeanyi mu omi ku lasiko to ko sinu omi iluwẹẹ to wa ninu ile baba rẹ, ki iṣe pe boya ẹnikẹni ṣe ohunkohun fun un tabi pe o ku iku to yatọ si eleyii.

Abọ iwadii ti awọn agbofinro maa n ṣe si oku to ba ku ki wọn le mọ iru iku to pa a tawọn oyinbo n pe ni autopsy lo fidi eleyii mulẹ.

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Eko, Benjamin Hundeyin, fidi ẹ mulẹ pẹlu, o ni abọ iwadii oku ọmọ naa ti jade, niṣe lo mu omi ku.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹwaa, to ṣẹṣẹ pari yii, ni okiki kan pe ọmọ ọdun mẹta naa jade laye. Wọn ni lasiko ti nani ti wọn ni ko maa tọju rẹ lọọ gba ipe ni ọmọkunrin naa lọ sibi odo iluwẹẹ atọwọda to wa ninu ile wọn, ti ko si sẹni to ri i.

O ti ku sinu omi naa ki wọn too ṣakiyesi pe inu omi yii lo wa lẹyin bii ogun iṣẹju ti wọn ti n wa a.

Eyi lo mu ki awọn agbofinro ko awọn mẹsan-an to wa ninu ile naa to n ba wọn ṣiṣẹ. Lẹyin-o-rẹyin ni wọn da awọn meji duro ninu wọn, iyẹn alase ati nani to n tọju ọmọ yii, ti wọn si ni ki awọn yooku maa lọ.

Awọn mejeeji ṣi wa lagọọ ọlọpaa di bi a ṣe n sọ yii. Abajade iwadii yii ni yoo si fopin si auyewuye tawọn kan n sọ pe wọn fun ọmọ naa ni nnkan jẹ ni.

Leave a Reply