Florence Babaṣọla ati Faith Adebọla
Ọjọ pataki ti ọpọ eeyan ti n reti lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2022 yii, paapaa nipinlẹ Ọṣun, tori ọjọ naa ni agbara ati eto iṣakoso ipinlẹ ọhun kuro lọwọ Gomina Gboyega Isiaka Oyetọla, ẹni to ti n tukọ ọhun bọ lati ọdun mẹrin sẹyin, ti Sẹnetọ Ademọla Adeleke si bọ sori aleefa gẹgẹ bii gomina tuntun ti wọn ṣẹṣẹ fibo gbe wọle.
Lati nnkan bii aago mẹfa idaji ọjọ naa ni papa iṣere nla ti ilu Oṣogbo ti kun fọfọ, bi awọn ọlọja ṣe n ta ni wọn n ra, bẹẹ awọn araalu n wọle sibẹ kẹtikẹti lati foju gan-an-ni gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun, Ademọla Adeleke, ti wọn ṣebura fun.
Ọpọ idi layẹyẹ ọjọ naa fi wa lọkan awọn eeyan, ti wọn si n foju sọna fun un. Ọkan ni pe latigba ti ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun kan niluu Ibadan ti yẹ aga nidii Ajagun-fẹyinti Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla gẹgẹ bii gomina lọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2010, ti wọn si kede Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla ti ẹgbẹ oṣelu Action Congress of Nigeria (ACN) nigba yẹn, gẹgẹ bii gomina, ni ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, ti gboorun ile ijọba Ọṣun gbẹyin, latigba naa si ni ibura-wọle sipo gomina l’Ọṣun ti kuro ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, ti ọpọ awọn ipinlẹ yooku maa n ṣe eto naa, to bọ si ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ti Arẹgbẹṣọla ṣebura-wọle lọdun naa lọhun-un.
Amọ bo ṣe ri nigba naa lọhun-un, o tun ti ri bẹẹ lọtẹ yii, Ademọla ti ẹgbẹ oṣẹlu PDP lo n gba iṣakoso lọwọ Oyetọla, awọn ara ipinlẹ Ọṣun ni wọn fibo juwe ile fun Oyetọla ninu ibo ti wọn di lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Keje, ọdun yii, ti wọn si gbegi dina fun un lati ṣe saa keji nipo gomina bii ti ọga rẹ, Arẹgbẹ. Saa meji ọlọdun mẹjọ ni Arẹgbẹṣọla lo ko too di pe Alhaji Gboyega Oyetọla ti ẹgbẹ oṣelu APC wọle ninu ibo gomina lọdun un 2018.
Bo tilẹ jẹ pe igbẹjọ ṣi n lọ lọwọ niwaju Tiribuna, iyẹn igbimọ idajọ to n gbọ awuyewuye to ba su yọ lasiko idibo, sibẹ, irawe ki i dajọ ilẹ ko sun oke, adaba o si naani a n kungbẹ, ina n jo ẹyẹ n lọ ni eto iṣejọba l’Ọṣun, eyi lo fa a ti wọn fi ṣebura fun Gomina tuntun, Ademọla Adeleke, lọjọ ti ofin sọ.
Eyi tumọ si pe lẹyin ọdun mejila ti wọn ti kuro nijọba, ẹgbẹ oṣelu PDP tun pada gba eeku ida iṣakoso nipinlẹ Ọṣun pẹlu bi adajọ agba ipinlẹ Ọṣun, Onidaajọ Bọla Adepele Ojo, ṣe bura fun Adeleke ni aago mejila ọsan ku iṣẹju mẹjọ.
Lara awọn eeyan pataki ti wọn wa nibi ayẹyẹ naa ni gomina ipinlẹ Ọṣun tẹlẹ, Ọmọọba Ọlagunsoye Oyinlọla, iyawo rẹ, Ọmọlọla Oyinlọla, igbakeji rẹ, Erelu Olusọla Ọbada.
Gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Emmanuel Udom, ti ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki, ti ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Rasidi Ladọja, igbakeji gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan, Oluṣọla Ẹlẹka ati bẹẹ bẹẹ lọ wa nibi eto naa.
Ọọni Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ogunwusi, Timi Ẹdẹ, Ọba Laminisa Lawal, Ataọja ilu Oṣogbo, Ọba Jimọh Ọlanipẹkun, Oluwoo ti ilu Iwo, Ọba Adewale Akanbi, Ọrangun Ila, Ọba Wahab Oyedokun, Orangun Oke Ila, Ọba Abọlarin, Salu Ẹdunabọn, Ọba Kehinde Ọladepo ati bẹẹ bẹẹ lọ ko gbẹyin nibẹ.
Bi awọn lẹgbẹlẹgbẹ ṣe wọ aṣọ ankoo, ni awọn lọgalọga lẹnu oṣiṣẹ ọba nipinlẹ Ọṣun naa duro wamuwamu lati ri i pe itan tuntun naa ṣoju awọn.
Lara awọn to tun wa nibi ayẹyẹ nla naa ni iyawo oludije funpo aarẹ orileede yii labẹ asia ẹgbẹ PDP, Oloye Titi Atiku, to jẹ ọmọ bibi ilu Ilẹsa, nipinlẹ Ọṣun, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin agba, ti aṣoju-ṣofin ati ti ileegbimọ aṣofin ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Akinade Akinbade, Alhaji Tajudeen Ọladipọ.
Bakan naa ni olorin taka-sufee nni, David Adeleke to jẹ ọmọ ẹgbọn gomina tuntun yii.