Adajọ ni ki wọn gbe ọlọpaa to yinbọn pa Ọmọbọlanle lọjọ Keresi lọ si Kirikiri

Faith Adebọla

Latari bo ṣe yinbọn pa Lọọya Ọmọbọlanle Raheem, pẹlu oyun inu ẹ lọjọ Keresi to lọ yii, ile-ẹjọ Majisreeti kan to fikalẹ sagbegbe Yaba, niluu Eko, ti paṣẹ ki wọn taari agbofinro to di afurasi ọdaran bayii, ASP Drambi Vindi, sọgba ẹwọn Kirikiri, n’Ikoyi, wọn ni ko ṣi lọọ maa gbatẹgun nibẹ titi ti igbẹjọ yoo fi tẹsiwaju lori ẹsun apaayan ti wọn fi kan an.

Owurọ ọjọ Ẹti, Furaidee, ọgbọnjọ, oṣu Kejila, ọdun 2022 yii, nileeṣẹ ọlọpaa wọ afurasi apaayan naa rele-ẹjọ, to si bẹrẹ si i kawọ pọnyin rojọ niwaju adajọ.

Bo tilẹ jẹ pe ẹsun kan ṣoṣo pere to da lori mimọ-ọn-mọ paayan ni wọn ka si i lẹsẹ, eyi ti wọn lo ta ko isọri kẹtadinlogun, idipọ kẹta, iwe ofin iwa ọdaran ipinlẹ Eko tọdun 2015, amọ igbẹjọ naa ko ti i bẹrẹ gidi. Awọn ọlọpaa ni awọn ṣi n ṣe iwadii, awọn si n ṣa ẹsun oriṣiiriṣii ti wọn yoo fi kan olujẹjọ naa jọ lọwọ. Wọn rọ ile-ẹjọ lati fun awọn laaye ki awọn gba imọran lọdọ ileeṣẹ ijọba to n ri si ẹjọ araalu, iyẹn Directorate of Public Prosecution.

Kọmiṣanna feto idajọ to tun jẹ ọga awọn adajọ nipinlẹ Eko, Ọgbẹni Moyọsọrẹ Onigbanjo, wa ni kootu naa, oun lo ṣaaju awọn lọọya yooku ti wọn ṣoju fun ijọba Eko to jẹ olupẹjọ, oun lo si rọ Adajọ kootu Majisireeti ọhun, Onidaajọ C. A. Adedayọ, lati paṣẹ ki wọn fi afurasi naa pamọ sẹwọn na.

Lara awọn amofin ti wọn wa pẹlu rẹ ni Amofin Titilayọ Shitta-Bay, Ọmọwe Babajide Martins, to jẹ agbẹjọro agba fun ijọba ipinlẹ Eko, Alakooso DPP, Adebayọ Haroun, Igbakeji rẹ, Yetunde Cardoso, Alamoojuto ẹka to n ri si ọrọ igbejọ nileeṣẹ ọlọpaa Eko, ati igbakeji rẹ, O. R. Saliu.

Amofin Moses Jah-Nissi lo ṣe agbẹjọro fun olujẹjọ, ASP Vandi. Ẹwu alawọ yẹlo ati ṣokoto dudu kan lonibaara rẹ wọ, bo ṣe kawọ pọnyin ni kootu naa.

Adajọ naa ni niwọn bi ofin ti faaye silẹ fawọn oluṣewadii ati ileeṣẹ ọlọpaa pe ki wọn ṣi fi olujẹjọ sẹwọn titi tiwadii yoo fi pari, nibaamu pẹlu isọri ọtalerugba ati mẹrin (264) iwe ofin iwa ọdaran Eko, o ni ki ASP Drambi lọọ lo oṣu kan gbako lọgba ẹwọn titi di ọgbọnjọ, oṣu Kin-in-ni, ọdun 2023, ti igbẹjọ yoo ma tẹsiwaju.

Tẹ o ba gbagbe, ayajọ ọdun Keresi, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kejila, ọdun yii, ni ariwo gba igboro kan pe ọkan ninu awọn ọlọpaa to n ṣayẹwo ọkọ labẹ biriiji Ajah, l’Erekuṣu Eko, ASP Drambi Vandi, ti yinbọn pa Abilekọ Ọmọbọlanle Raheem,  lọọya ẹni ọdun mọkanlelogoji kan, lasiko tobinrin naa atawọn mọlẹbi ẹ n bọ lati ṣọọṣi ati ile ounjẹ ti wọn ya si lati ra nnkan ipanu lọjọ ọdun.

Lẹyin ọrọ yii ni ọkọ oloogbe naa, Gbenga Raheem, ati iya rẹ, Abilekọ Salam, fidi ẹ mulẹ pe, oyun ibeji to ti pe oṣu meje wa nikun oloogbe yii lasiko ti wọn da ẹmi ẹ legbodo.

Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa ti rọ ajọ to n ri si ọrọ awọn ọlọpaa, Police Service Commission (PSC), lati gba iṣẹ lọwọ Vandi, ko le ṣee ṣe fun un lati rẹnu rojọ to ko si naa daadaa.

Leave a Reply