Ọrẹoluwa Adedeji
Pẹlu bi awọn araalu ṣe n to rẹrẹẹrẹ lawọn banki kaakiri ilẹ wa lati paarọ owo atijọ ti wọn ni lọwọ si tuntun to ṣẹṣẹ jade bayii, ti igbesẹ yii si n ko inira nla ba wọn, Olori orileede wa, Aarẹ Muhammadu Buhari, ti sọ pe gbogbo ohun to ba wa ni ikapa ijọba ni yoo ṣe lati fopin si wahala naa, ti igbesẹ pipaarọ owo Naira ilẹ wa yii yoo rọrun fun awọn araalu, paapaa ju lọ awọn mẹkunnu.
O ni eto pipaarọ owo Naira ki i ṣe lati fi ni araalu lara, awọn oniwa ibajẹ ti wọn n kowo pamọ, awọn to n ṣe agbodegba fawọn afẹmiṣofo atawọn ti wọn n ṣowo ti ko ba ofin mu ti wọn n ko owo rẹpẹtẹ sile lawọn tori rẹ gbe igbesẹ yii.
Ọjọ Abamẹta lo sọrọ naa nipasẹ Oludamọran pataki rẹ lori eto iroyin, Sheu Garba. Buhari ṣalaye pe awọn igbesẹ ti awọn gbe yii pọn dandan lati dena awọn ayederu owo, iwa ibajẹ, awọn ti wọn n ṣe agbodegba fun awọn afẹmiṣofo ati lati jẹ ki ọrọ aje ilẹ wa to ti n ṣojojo lagbara si i.
O fi kun un pe awọn ko salai mọ pe inira yoo wa fun awọn mẹkunnu to jẹ pe ọpọ wọn lo n ko iwọnba owo ti wọn ni sile, ṣugbọn ki i ṣe pe awọn fẹẹ fi igbesẹ pipaarọ owo yii ni wọn lara. O ni gbogbo ọna lawọn yoo gba lati ri i pe igbesẹ pipaarọ owo yii di irọrun fun wọn. O ni banki apapọ ilẹ wa pẹlu awọn banki kerejekereje nilẹ yii ti n gbe igbesẹ lati ri i pe pinpin owo Naira tuntun yii ya kankan, ti ko fi ni i ni araalu lara.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kọkanla, ọdun to kọja, ni Buhari ṣiṣọ loju owo Naira tuntun naa. Lasiko ifilọlẹ owo ọhun ni Olori banki apapọ ilẹ wa (CBN), Godwin Emefiele, ti sọ pe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kin-in-ni, ọdun yii, ni gbigba owo Naira atijọ yoo kasẹ nilẹ, ti awọn araalu ko ni i le na an mọ. O sọ nigba naa pe ijọba ko ni i fi ọjọ kun ọjọ ti awọn ti sọ yii.
Bakan naa ni banki apapọ yii koro oju si awọn banki ti wọn ba tun n ko owo atijọ yii sẹnu ẹrọ ipọwo wọn, ATM. Ijiya nla ni wọn kede pe awọn yoo fun banki to ba n ṣe bẹẹ. Eyi lo fa a ti awọn banki naa ko fi ko owo ọhun sẹnu ẹrọ mọ, bẹẹ ni wọn ko ko owo tuntun ti ijọba ni ki araalu maa na bayii sibẹ.
Inira ti ko ṣee fẹnu sọ lọrọ naa si ti mu ba awọn araalu, paapaa ju lọ awọn olokoowo keekeeke ti wọn ko le maa lo ẹrọ ayelujara lati ṣe owo wọn. Ọpọ awọn to lọ si banki lati gba owo tuntun yii ko ri i gba, wahala kekere si kọ lo koju ọpọ awọn to fẹẹ fi owo atijọ wọn si banki ko ma baa di kọndẹ mọ wọn lọwọ n ri.
Titi di ba a ṣe n sọ yii ni ọpọ araalu ko ti i ri owo tuntun yii gba, awọn oniṣowo keekeeke mi-in ko si gba owo atijọ yii mọ, eyi to mu ki gbogbo nnkan le koko fawọn araalu.
Ṣugbọn pẹlu ohun ti Buhari sọ yii, awọn kan ti wọn ba akọroyin ALAROYE sọrọ ti sọ pe to ba jẹ loootọ ni pe igbesẹ ti wọn gbe yii yoo mu ilera ba ọrọ aje wa to ti n ṣojojo, ti yoo si fopin si awọn olubi ẹda kan to ko owo tabua sile, nibi ti awọn kan ko ti lowo lọwọ, a jẹ pe igbesẹ to daa ni. Ẹbẹ kan ti wọn kan n bẹ ijọba ni pe ki wọn tete wa gbogbo ọna ti owo naa yoo fi wa nita fun lilo awọn araalu, paapaa ju lọ awọn mẹkunnu ti ko lẹnikan.