Monisọla Saka
Ni nnkan bii wakati diẹ si ọjọ idibo gomina nilẹ yii, Ṣẹyẹ Dairo, ti i ṣe adari ikọ eto ipolongo fun oludije funpo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP, Abdulazeez Ọlajide Adediran, tawọn eeyan mọ si Jandor, ti ja a ju sọlọpọn.
Dairo to fi erongba ẹ han ninu lẹta to kọ ranṣẹ ko ri nnkan kan gunmọ sọ lori idi to fi fẹgbẹ naa silẹ niru akoko bẹẹ.
Amọ ṣa o, ọkunrin naa fẹmi imoore rẹ han si Jandor, pẹlu bo ṣe fun un lanfaani lati dipo adari igbimọ eleto ipolongo ibo rẹ mu.
Pupọ awọn to dipo kan-an-rin kan-an-rin mu lẹgbẹ naa ni wọn ti n fẹgbẹ oṣelu PDP silẹ lọkọọkan ejeeji, lati lọọ dara pọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC tabi ẹgbẹ Labour Party, gẹgẹ bi ibo gomina ti yoo waye lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, ṣe ku ọla.
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ki Dairo ma ṣiṣẹ fun Gbadebọ Rhodes-Vivour, ti i ṣe oludije dupo gomina lẹgbẹ oṣelu Labour Party, lọjọ Satide yii.
Laipẹ yii ni wọn ri ọkunrin to n dari ipolongo ibo Jandor yii nibi eto kan ti igbakeji alaga apapọ fẹgbẹ oṣelu PDP tẹlẹ, Oloye Ọlabọde George, ṣe, nibi to ti ko awọn ọmọ ẹgbẹ Ọmọ Eko Pataki ṣodi lati buwọ lu Gbadebọ Rhodes-Vivour, ti ẹgbẹ oṣelu Labour Party, gẹgẹ bii oludije ti wọn n ṣatilẹyin fun.
Ṣugbọn lasiko to n sọrọ nibi ipade awọn oniroyin to ṣe lọọfiisi rẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹta, ọdun yii, Jandor la a mọlẹ pe ko ti i si ọmọ ẹgbẹ awọn to ṣe ipolongo ibo bi ọkunrin to ṣadeede fẹgbẹ naa silẹ lọsan-an kan oru kan yii ṣe n ṣe, lati bii oṣu meloo kan sẹyin.
O ni, “Ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Eko ko dara pọ mọ ẹgbẹ kankan o, ki gbogbo awọn ọmọ Naijiria dibo fun PDP ninu ibo to n bọ yii. Irọ nla ni awọn ahesọ ọrọ ti mo n gbọ pe mo ti juwọ silẹ fun oludije lẹgbẹ oṣelu mi-in”.
O tẹsiwaju pe loootọ loun n ri bawọn eeyan ṣe n fi ẹgbẹ oṣelu kan silẹ lọ sibomi-in, lati APC lọ si PDP, ati lati ẹgbẹ Labour lọ si PDP atawọn mi-in bẹẹ. O ni asiko ẹ naa la wa yii, ati pe nitori bẹẹ naa ni wọn ṣe n pe e ni eto idibo gbogbogboo.