Nitori ti wọn ni ko ma luyawo ẹ pa, Ogunwusi gun araale rẹ lọbẹ pa l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Okunrin ẹni ọdun mejilelogun kan, Fẹmi Ogunwusi, nikan lo le ṣalaye iru inu buruku to bi i to fi gun ọkunrin ti wọn jọ n gbele pa. O ti huwa naa tan ki oju rẹ too walẹ pe ẹwọn loun n kọ lẹta si yii. Awọn ọlọpaa ipinlẹ Ekiti si ti nawọ gan an, o ti wa lakata wọn to n ṣalaye ohun to ri lọbẹ to fi waro ọwọ lori iṣẹlẹ naa.

Gẹgẹ bi awọn eeyan adugbo naa ṣe sọ, wọn ní Ogunwusi to bi ọmọ meji, to si n ṣiṣẹ ọkada lo ni ede aiyede pẹlu iyawo rẹ ni kutukutu owurọ Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu yii, lori ọrọ owo kan.

Eyi la gbọ pe o fa a ti baale ile naa fi bẹrẹ si i lu iyawo rẹ bii ẹni lu baara. Lilu to n lu obinrin naa pọ, eyi lo mu ki awọn alajọgbele wọn gba obinrin naa lọwọ rẹ, ti wọn sì lọọ mu un pamọ síbi ti ẹnikẹni ko mọ.

ALAROYE gbọ pe igbesẹ ti awọn araale Ogunwusi gbe yii lo tubọ bi ọkunrin ọlọkada yii ninu, lo ba sọ fun ọkan lara awọn ti wọn jọ n gbele naa pe ti ko ba lọọ mu iyawo oun jade nibi ti wọn fi i pamọ si, oun yoo ran an lọrun airotẹlẹ.

Lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn ti wa lori ọrọ naa ni baale ile yii wọle lọ, o si lọọ mu ọbẹ kan jade, lo ba fi gun araale wọn yii ni ọọkan igbaaya rẹ, bẹẹ lọkunrin yii ṣubu lulẹ. Awọn araadugbo ni wọn gbe e digbadigba lọ sileewosan aladaani kan to wa ni adugbo naa.

Lẹyin iṣẹju die ni awọn dokita sọ fun wọn pe o ti jade laye. Iku ọkunrin yii lo fa ọpọ ero ti wọn ya bo ile iwosan naa pe awọn fẹẹ ri oju ọkunrin apaayan ọhun.

Awọn eeyan adugbo naa lo pe awọn ọlọpaa, awọn agbofinro lo si pada gbe oku ọkunrin naa lọ, iṣẹ nla ni wọn ṣi ṣe ki wọn too ri Ogunwusi mu kuro nibẹ laaye, nitori awọn ero to ti duro lati da sẹria fun un. Awọn ọlọpaa ni wọn yinbọn soke lati le awọn ero sa ti wọn fi ri ọkunrin naa gbe lọ si teṣan wọn.

Nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Sunday Abutu, sọ pe ọdaran naa ti wa ni akata awọn ọlọpaa.

O fi kun un pe wọn ti gbe oku ọkunrin to pa yii pamọ sile igbokuu-pamọ si nileewosan ijọba to wa ni Ado-Ekiti. Abutu ni iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply