Ọlawale Ajao, Ibadan
Obinrin oniṣowo kan, Alhaja Zainab Mabinuori, ti rọ kootu ibilẹ Ile-Tuntun to wa laduugbo Mapo, n’Ibadan, lati fopin si ibaṣepọ ọlọdun mọkanla to wa laarin oun atọkọ ẹ, Alhaji Nurudeen Mabionuori. O lọkunrin naa ti fẹẹ fi ibalopọ baye oun jẹ.
Iya to fi adugbo Muslim-Odinjo, n’Ibadan, ṣebugbe yii ṣalaye pe gbogbo igba ti oun atọkọ oun ba ti jọ laṣepọ laisan maa n ṣe oun, idi si niyẹn ti oun ko ṣe gba fun un mọ, ko ma fi ibalopọ ba toun jẹ.
“Ninu oṣu kẹta, ọdun 2014, emi atiwọn ni ibalopọ gẹgẹ bii tọkọ-tiyawo, ba a ṣe pari ẹ tan ni gbogbo agọ ara mi daru patapata, ti mi o si gbadun ara mi mọ”, bẹẹ lobinrin oniṣowo naa sọ.
O tẹsiwaju pe “Mo ni Alaaji, ki lo de, latigba ta a ti laṣepọ ni mi o ti gbadun ara mi mọ, ki lo ṣẹlẹ. Wọn ni eéwo kan lo mu awọn nibi nnkan ọmọkunrin, mo ni ẹ yaa tọju ara yin o.
“Awọn ko le ṣe ki wọn ma ba obinrin laṣepọ ni tiwọn, mo ni ki wọn yaa maa ri i pe wọn n lo rọ́bà idaabobo nigbakuugba ti wọn ba ti fẹẹ sun mọ mi. Ṣugbọn bi wọn ṣe n lo o to naa, gbogbo igba ta a ba jọ laṣepọ laisan maa n ṣe mi. Idi niyẹn ti mi o ṣe gba fun wọn lati sun mọ mi mọ.”
Alhaji Nurudeen lo pẹjọ lati kọ iyawo ẹ silẹ, ṣaaju lo si ti ṣapejuwe Zainab gẹgẹ bii oniwahala obinrin.
Ọkunrin oniṣẹ ọwọ yii fi kun un pe “Lọsẹ to kọja, nitori pe mi o ti i fun un lowo ounjẹ, o (Zainab) fa aṣọ ya mọ mi lọrun, o mu kọkọrọ mọto mi ati bata mi, o loun ko ni i jẹ ki n jade lọ sibi iṣẹ, afi ti mo ba too fun oun lowo.
“Gbogbo ẹbi lo ti da si ọrọ ija wa, sibẹ, iyawo mi ki i yee fa ijangbọn. Ko jẹ ki gbogbo akitiyan ẹbi awa mejeeji lati ri i pe alaafia jọba laarin wa seso rere.”
Olori igbimọ awọn adajọ kootu naa, Oloye Henry Agbaje ti sun igbẹjọ naa si Ọjọruu, ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, ọdun 2020 yii, iyẹn Wẹsidee ọsẹ to n bọ yii, nigba to gba awọn tọkọ-tiyawo naa niyanju lati ma ṣe ba ara wọn ja tabi fa wahala ko too di ọjọ naa.