Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ
Gomina ipinlẹ Ondo, Ọnarebu Lucky Orimisan Ayedatiwa, ti gba awọn ọba ilẹ Yoruba nimọran lori ọna ti wọn fi n lo agbara wọn lori awọn araalu.
Gomina parọwa yii nipasẹ Igbakeji rẹ, Oloye Ọlayide Ọdunlami, lasiko to n gbe ọpa aṣẹ fun Lárògbò ti Àkótógbò tuntun, Ọba Michael Elumaro, Akinfọlarin niluu Àkótógbò, nijọba ibilẹ Irele, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2024 yii.
Ayedatiwa ni ohun to yẹ ko jẹ awọn ọba logun lẹyin ti wọn ba ti gba ọpa aṣẹ ni lati wa gbogbo ọna ti irẹpọ, iṣọkan ati ifẹ yoo fi tubọ fẹsẹ mulẹ si i laarin awọn ti wọn n dari, nitori ipa pataki ti iṣọkan nko ninu idagbasoke agbegbe kọọkan.
O ni lara ohun ti oun tun n reti lati ọdọ awọn ọba alaye ọhun ni siṣowo pọ pẹlu ijọba ninu akitiyan ti wọn n ṣe lori pipeṣe aabo to peye fawọn araalu, nitori iṣejọba Ayedatiwa ti ṣetan lati fọ ipinlẹ Ondo mọ tonitoni, ti ko si ni i si ibikíbi lati foju pamọ si fawọn ọdaran rara.
O ni idi ree ti ijọba oun fi gbe agbara nla wọ awọn ẹṣọ Amọtẹkun atawọn ẹsọ aabo yooku to wa nipinlẹ Ondo, ti oun si tun ri i daju pe gbogbo irin-iṣẹ ti wọn nilo lati fi gbogun ti awọn ọdaran pata loun n ṣeto fun wọn.
Ayedatiwa waa fi asiko ọhun ki Ọba Michael ku oriire gigun ori itẹ awọn baba nla rẹ, eyi to ti ṣofo lati ogunjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2009.