Ijọba pin nnkan ija loriṣiiriṣii fawọn ẹṣọ alaabo l’Ekiti

 Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ni ilakaka ijọba ipinlẹ Ekiti lati fi opin si eto ijinigbe ati iṣeku pa ni ni ipinlẹ Ekiti, ìjọba ipinlẹ naa ti pin awọn ohun ija loriṣiiriṣii fun awọn ẹṣọ alaabo to wa nipinlẹ naa.

Nigba to n pin awọn ohun ija naa, Igbakeji gomina ipinlẹ naa, Arabinrin Monisade Afuyẹ, sọ pe ijọba gbe eto naa kalẹ lati fopin si eto aabo ti ko nipọn to nipinlẹ naa. O fi kun un pe ijọba ti ṣetan lati fopin si eto aabo ti ko ṣe daadaa lawọn apa kan nipinlẹ ọhun.

Igbakeji gomina yii juwe bi awọn agbebọn ṣe ṣeku pa awọn ọba alaye meji, ati bi awọn ajinigbe ṣe ko awọn ọmọọleewe laipẹ yii gẹgẹ bii ohun to mu ifasẹyin ba ipinlẹ Ekiti. O ṣalaye pe pinpin ohun ija naa nijọba ṣe agbekalẹ rẹ lati ro awọn ẹṣọ alaabo lagbara.

Afuyẹ sọ siwaju pe pinpin ohun ija naa ni ajọ to n pese aabo loju omi (NIMASA) ati ifọwọ-sọwọpọ ìjọba ipinlẹ Ekiti ṣe agbekalẹ lati ro awọn ẹṣọ alaabo lagbara lati dena iṣẹlẹ ijinigbe ati iṣekupani nipinlẹ naa lọjọ iwaju.

O fi kun un pe ìjọba Gomina Oyebanji ti ṣetan lati pese aabo to peye fun awọn olugbe ipinlẹ naa, pẹlu bii ijọba ṣe pin owo ti ko din ni miliọnu marundilaaadọta (N45m) fawọn eeyan ti ìṣẹlẹ búburú ṣẹlẹ si lọdun 2023.

Igbakeji gomina yii sọ pe ilakaka ati akitiyan gomina tubọ yọrí si rere pẹlu bi ọwọ awọn ẹṣọ alaabo ṣe tẹ awọn to sẹku pa ọba meji nipinlẹ Ekiti, ati bi ijọba ṣe ṣe ohun gbogbo lati ri i daju pe awọn ọmọ ile-iwe ti awọn ajinigbe ji gba ominira pada.

Ninu ọrọ rẹ nibi eto yii, ọga agba ileeṣẹ to n ri sọrọ pajawiri nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Oludare Aṣaolu, gboṣuba kare fun ijọba apapọ pẹlu idasi ati akitiyan rẹ l’akooko iṣẹlẹ ijinigbe ati iṣekupani to ṣẹṣẹ waye tan nipinlẹ Ekiti.

O ṣalaye pe idasi ijọba apapọ ati ilakaka gomina ipinlẹ Ekiti lo yọri si rere pẹlu bi wọn ṣe tete tu awọn ọmọ ileewe ti wọn ko naa silẹ, ati bi wọn ṣe ri i awọn tio da ẹmi awọn ọba alaye meji legbodo nipinlẹ naa.

 

 

Leave a Reply