Nitori iṣẹlẹ ijinigbe ojoojumọ, ibẹru gb’ọkan awọn eeyan Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Inu ibẹru nla lawọn eeyan Akoko ati Ọwọ, eyi to wa lẹkun Ariwa ipinlẹ Ondo, wa lọwọlọwọ, nitori iṣẹlẹ ijinigbe to n figba gbogbo waye lawọn agbegbe ọhun.

Ohun to tun waa mu ki ibẹru yii peleke si i lọkan awọn araalu to wa lawọn agbegbe wọnyi ni tawọn ero ọkọ bọọsi GUO ti wọn tun ji gbe loju ọna Akunnu Akoko si Ayẹrẹ, lopin ọsẹ to kọja, lẹyin ti wọn pa awakọ ọkọ ero ọhun nipakupa.

Gbogbo bi wọn ṣe lawọn ẹṣọ alaabo lati ipinlẹ Ondo ati Kogi n gbiyanju to pẹlu pe ni kete tiṣẹlẹ buruku ọhun ba ti sẹ ni wọn ti n fọn sinu igbo lati wa awọn ti wọn ji gbe naa ni awari, eyi ko ti i so eeso rere kankan titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ lọwọ.

Kọmisanna ọlọpaa tuntun ti wọn ṣẹṣẹ gbe wa sipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Abayọmi Peter Ọladipọ, ṣalaye ninu ọrọ to b’awọn oniroyin sọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2024 yii, ni oun gbọ pe awọn ajinigbe ọhun ti n kan si awọn ẹbi awọn ti wọn ji gbe naa lati beere owo itusilẹ lọwọ wọn.

Iṣẹlẹ yii ni wọn lo ti da jinni jinni nla ṣọkan awọn eeyan agbegbe naa, paapaa awọn agbẹ, ti ibẹrubojo ko si jẹ ki wọn laya lati lọ sinu oko wọn lọọ ṣiṣẹ mọ.

Awọn agbẹ agbegbe ta a gbọ pe ọrọ yii kan ju lọ ni: Àjọwá, ìkákùmọ̀ ati Àúga Akoko, wọn ni gbogbo wọn ni wọn ti pa oko wọn ti, nitori ibẹru awọn Fulani ti wọn n gbe awọn nnkan ija oloro kiri oko oloko.

Ọkan ninu awọn agba ilu kan to ba wa sọrọ lori iṣẹlẹ ọhun ni ko si ani- ani pe itu buruku tawọn oniṣẹẹbi wọnyi n pa lagbegbe Akoko ti jẹ ki awọn ire-oko atawọn nnkan jíjẹ wọn kọja fifẹnu sọ.

Yatọ si tawọn agbẹ ti wọn ko r’oju raaye lọ sinu oko wọn mọ nitori ibẹru pipa tabi jiji gbe, awọn obinrin to yẹ ki wọn maa kiri tabi ko awọn ounjẹ lọọ ta lọja tabi kiri kaakiri igboro lo ni wọn ko le jade ṣe bẹẹ mọ lasiko yii nitori awọn ajinigbe.

O ni ẹbẹ l’awọn n bẹ ijọba lati tete wa nnkan ṣe sọrọ ipenija eto aabo to n ba awọn eeyan ẹkun Ariwa finra, ki n nnkan too bajẹ kọja atunṣe.

Leave a Reply