Ọga ọlọpaa kowo jẹ, wọn ti yọ ọ bii jiga nipo

Monisọla Saka

Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Delta, CP Abaniwọnda Olufẹmi, ti paṣẹ pe ki wọn gbọn SP Ibrahim Ishaku, ti i ṣe ọga ọlọpaa lẹka to n ri si iwa ọdaran, Divisonal Crime Officer (DCO), ni tẹsan Abraka, nipinlẹ Delta, danu, nitori ẹsun pe o ko owo to to miliọnu meji ataabọ Naira jẹ ti wọn fi kan an.

Ninu atẹjade ti DSP Edafe Bright, ti i ṣe agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ naa fi lede l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun yii lo ti ni, “Lẹyin ti ẹsun ikowojẹ ati ilọnilọwọgba miliọnu meji Naira le diẹ ti wọn ni ọga ọlọpaa DCO 2, tẹsan Abraka, ko jẹ de etiigbọ Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ yii, CP Abaniwọnda Olufẹmi, o ti paṣẹ pe ki ọga ọlọpaa teṣan Abraka, nipinlẹ Delta, waa kawọ pọnyin rojọ niwaju olu ileeṣẹ ọlọpaa, pẹlu SP Ibrahim Ishaku, ti wọn fẹsun kan.

“Lẹyin ti kọmiṣanna gbọ nipa iṣẹlẹ to n ba ni ninu jẹ ọhun lo paṣẹ pe ki wọn yọ SP Ibrahim Ishaku danu werewere bii ẹni yọ jiga, ki wọn si pin iwe ẹsun fun un lati ṣalaye ara ẹ lori aṣemaṣe ọhun”.

Kọmiṣanna ọlọpaa to ni igbesẹ yii yoo jẹ ẹkọ fawọn ọbayejẹ to ku laarin awọn agbofinro sọ pe, ohun ko ni i tẹ̀tì ninu fifi iya to tọ jẹ ọlọpaa yoowu ti aje iwa ibajẹ ba ṣi mọ lori, labẹ akoso oun.

 

Leave a Reply