Nitori owo tikẹẹti, agbero fun onikẹkẹ lọrun pa

Monisọla Saka

Ọkan lara awọn agbero to n jawe fawọn onimọto ati ọlọkada nipinlẹ Delta, Task Force, Tunde, tawọn eeyan mọ si Ọbama, ti gbẹmi Augustine Williams, ọkunrin onikẹkẹ Maruwa kan, lasiko ti irinwo Naira owo tikẹẹti (400) da ede aiyede silẹ laarin wọn.

Lagbegbe Awolọwọ, Sapele, nipinlẹ Delta, niṣẹlẹ ọhun ti waye nirọlẹ ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun yii.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Vanguard ṣe sọ, Tunde da kẹkẹ Augustine duro lọjọ naa lati gba owo tikẹẹti ti wọn maa n ja lojoojumọ lọwọ ẹ ni, ṣugbọn ọrọ naa di ariyanjiyan nigba ti Tunde fẹẹ yọ kọkọrọ kẹkẹ ọkunrin naa pẹlu agidi.

Ọna lati gba ara ẹ ati kẹkẹ ẹ silẹ ni Augustine fi di Tunde lọwọ mu, tọrọ naa si pada di ija gidi. Lojiji ni wọn ni Tunde di ọkunrin naa lọrun mu, ti Augustine si nalẹ gbalaja.

Ẹni kan tọrọ ṣoju ẹ, amọ to ni ki wọn forukọ bo oun laṣiiri ni, “Bi Augustine ṣe nalẹ lo bẹrẹ si i mi tupetupe, to n japoro nibi to ṣubu si. A gbiyanju lati ji i saye pada ka a too gbe e digbadigba lọ sileewosan, ṣugbọn tawọn dokita ni ẹmi ti bọ lara ẹ”.

Pẹlu ibinu ati aroye pe wahala ati iya tawọn to n gbowo tikẹẹti fi n jẹ awọn lojoojumọ ti pọ ju ni wọn fi ṣa ara wọn atawọn ọlọkada jọ lati wọ igboro pẹlu ifẹhonu han, amọ awọn agbofinro da wọn lọwọ kọ.

Awọn ẹgbẹ ọlọkada ati maruwa, ẹka Sapele, nipinlẹ Delta, Motorcycle and Tricycle Operators Association (COMTOA), ti ni awọn ko mọ nipa iku ọkunrin onimaruwa ti wọn lo ku.

Ninu atẹjade ti igbakeji alaga ẹgbẹ naa, Destiny Uhria, fi sita, lo ti sọ pe afurasi to paayan ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ awọn.

“Ẹgbẹ yii n fi akoko yii kede fun gbogbo eeyan pe ẹni ti wọn lo paayan ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wa, tabi ara awọn to n gbowo tikẹẹti ti wọn n pe ni task force”.

Gẹgẹ bi alaye iweeroyin  Daily Post, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Delta, DSP Bright Edafe, ti fidi ẹ mulẹ pe afurasi kan ti wa latimọle awọn to wa ni Sapele, lori iku Ọgbẹni Augustine.

 

Leave a Reply