Ijọba ṣawari mọṣuari tawọn agbenipa n gbe oku si n’llọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji yii, ni ijọba ipinlẹ Kwara, ti mọsuari kan pa ni No. 6, Gaa-Àkàǹbí, nikorita Pipeline, nijọba ibilẹ Guusu, Ilọrin (South), Ilọrin fẹsun pe wọn da a silẹ lọna aitọ, to si ṣokunfa ajakalẹ arun lagbegbe naa.

Kọmisanna lẹka eto elera nipinlẹ Kwara, Dokita Amina Ahmed El-Imam, Akọwe agba nileeṣẹ to n ri si eto ilera ni Kwara, Dokita Abubakar Ayinla, ati adari ẹka to n kọ nipa eto ilera ni Kwara, Dokita Musiliyu Odunaiya, ni wọn lọọ tilẹkun mọṣuari ọhun to wa ni ileewosan Ọmọseni, lagbegbe Gaa-Àkàǹbí, fẹsun pe wọn ki i ṣe itọju gbogbo oku ti wọn ba ti ko si mọsuari ọhun.

El-Imam, ni awọn gbe igbeṣẹ naa latari pe ijọba ko fọwọ si idasilẹ mọsuari ọhun, tawọn si fẹ ki gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara jina si gbogbo awọn iwa kọ tọ bayii.

O tẹsiwsju pe awọn olugbe agbegbe naa lo kegbajare sijọba lori iwa aitọ tawọn kan hu nipa gbigbe oku si mọṣuari naa, leyi ti wọn kan ko sibẹ lai ṣe itọju wọn, ti wọn si ni o le ṣokunfa ajakalẹ arun lagbegbe naa.

O ni ijọba ko ni i gba ohunkohun to maa ṣakoba fun ilera araalu paapaa ju lọ awọn olugbe ipinlẹ Kwara.

Lafikun, ALAROYE gbọ pe Al-Maroof Afọlayan, ti awọn ọlọpaa mu pe o ṣeku pa ọrẹ rẹ, Mustapha Balogun, mọṣuari Ọmọsebi yii kan naa lo lọọ ju oku ẹ si. Bakan naa ni wọn sọ pe gbogbo awọn alagbara ti wọn ba ti ṣeku pa ẹni kan, mọṣuari yii naa ni wọn aa ju oku ẹ si. Awọn ẹṣọ alaabo ni ọwọ wọn ko mọ ninu iwa buruku naa.

Ọkan lara awọn olugbe agbegbe naa to ni ka forukọ bo oun laṣiiri sọ pe, o ṣee se ki wọn maa lo mọsuari naa lati maa yọ ọkan awọn eeyan. Fun idi eyi, wọn ni o yẹ ki ijọba mu gbogbo awọn to n ṣiṣẹ ni ile-igbokuupamọ-si ọhun fun iwadii to peye.

Awọn alaṣẹ nileeṣẹ ẹka eto ilera ni Kwara, sọ pe awọn ti kọkọ ti mọṣuari ọhun ninu oṣu Kẹwaa, ọdun to kọja, ṣugbọn ti wọn tun si i pada, ti wọn si tun n lo o fun iṣẹ buruku.

Leave a Reply