O ṣẹlẹ, ileewe ti wọn ti n kọ ẹkọ nipa Yahoo lọwọ EFCC ti tẹ awọn eleyii

Ibrahim Alagunmu

Afi bii ẹni pe ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu kumọkumọ nilẹ yii, iyẹn Economic and Financial Crimes Commission (EFCC), ṣọdun ikore awọn afurasi ọdaran pẹlu bi wọn ṣe ri mẹrinla ko ninu awọn afurasi onijibiti lọwọ lọjọ kan ṣoṣo. Ileewe ti wọn ti n kẹkọọ nipa jibiti lilu lori ayelujara lọwọ ti tẹ wọn niluu Makurdi, ipinlẹ Benue.

Orukọ awọn afurasi ọhun ni, Asongu Terungwa, Aese Sonter, Nyoosu Terungwa, John Kator, Udi Micheal Aodona, Terungu Mnyam, Iorwuese Terhide, Ule Francis, Imoter Gloor Emmanuel ati Samuel Lubem.

Awọn yooku ni Wergba Tertamge, Erukaa Ephraim, Agenale Franklin ati Abechi Toryila.

Ajọ naa ni nile oniyara mẹta kan to wa l’Opopona Achusa, niluu Makurdi, tawọn afurasi naa lo gẹgẹ bii aaye lati maa kẹkọọ nipa jibiti ori ayelujara ni ọwọ ti tẹ gbogbo wọn.

Awọn ẹru ti wọn ba lọwọ wọn ni laptop, ATM kaadi, awọn foonu rẹpẹtẹ, Firman jẹnẹretọ kan ati ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Corolla kan.

Lopin gbogbo iwadii ajọ EFCC  lawọn afurasi ọdaran wọnyi yoo foju ba ile-ẹjọ, iyẹn bi nnkan ko ba yipada lẹyin iwadii akọroyin wa.

 

Leave a Reply