Emi l’Akeredolu fontẹ lu gẹgẹ bii ẹni to maa di gomina lẹyin rẹ ko too ku- Ayedatiwa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Gomina Lucky Orimisan Ayedatiwa ti ni ọga oun, iyẹn Oloogbe Rotimi Akeredolu, ti fontẹ lu oun gẹgẹ bii ẹni to maa rọpo rẹ gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ondo ninu eto idibo to n bọ ko too jade laye lọjọ kẹrijdinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 2023 ta a ṣẹṣẹ pari yii.

Ayedatiwa sọrọ yii ninu ipade nla kan to ṣe pẹlu awọn oniroyin, awọn ṣọrọṣọrọ atawọn olori ẹgbẹ kan ninu gbọngan to wa lọfiisi gomina, ni Alagbaka, niluu Akurẹ, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Keji, ọdun yii.

O ni gbogbo ohun to wa lọkan Arakunrin ṣaaju iku rẹ ni pe oun Ayedatiwa ni yoo di gomina ipinlẹ Ondo lẹyin ti Aketi ba pari saa rẹ lọdun 2025, ti awọn ọmọ igbimọ ijọba ti wọn ṣẹṣẹ kogba sile naa si le jẹrii si i, nitori Aketi ko fi igba kankan fi aṣiri yii pamọ pẹlu bo ṣe maa n sọ ọ ni gbogbo igba ti awọn ba ti wa ninu ipade pẹlu rẹ.

Ọnarebu Ayedatiwa ni gbogbo ẹnu loun fi n sọ ọ pe ko si ede aiyede kankan laarin oun ati Akeredolu nigba aye rẹ, bẹẹ ni oun ko si dalẹ rẹ rara, ni ibamu pẹlu irọ ati ariwo tawọn eeyan kan n pa kiri.

O ni awọn kan ti wọn mọ bi nnkan ṣe n lọ laye Aketi, ti wọn si ti mọ ibi ti ọrọ rẹ yoo pada ja si ni wọn ko ara wọn jọ nigba naa lati fẹẹ fi tipatipa yẹ aga mọ oun nidii, nitori imọtara tiwọn nìkan.

Awọn eeyan ọhun ati irọ wọn lo ni oun ṣetan lati tu asiri wọn nigba to ba to akoko.

Inu oṣu Kẹwaa, ọdun 2020, ni Aketi kọkọ yan Ayedatiwa gẹgẹ bii igbakeji rẹ, lẹyin ti ija nla bẹ silẹ laarin oun ati Ọnarebu Agboọla Ajayi, ẹni ti wọn jọ fi ibo gbe wọle lọdun 2016, fun saa kin-in-ni.

Loju gbogbo eeyan ni Akeredolu si ti n pọn Ayedatiwa lọjọ ti wọn n bura wọle fun un lẹẹkeji, lọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2021, to si n kan saara si i fun jíjẹ oloootọ rẹ lati igba ti awọn ti mọra.

Akeredolu sọ ninu asọtẹlẹ rẹ lọjọ naa lọhun-un pe Ayedatiwa yẹ fun ipo igbakeji gomina ti oun yan an si, nitori akitiyan ati aduroti rẹ, ati pe igbagbọ oun ni pe ṣe lawọn mejeeji yoo jọ pari saa tuntun ti awọn jọ bẹrẹ nigba naa.

O ni oun ti ko ọpọlọpọ awọn ọmọlẹyin jọ, ti Ayedatiwa si le bẹrẹ lati ibi ti oun ba iṣẹ de, nitori o ti di dandan fun oun Akeredolu ki oun maa duro sẹyin diẹdiẹ, ki igbakeji oun le lanfaani lati maa goke si i.

Leave a Reply