Faith Adebọla
Ọrọ kan to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara bayii ni bi gbajugbaja ọkunrin alafẹ to n mura bii obinrin nni, Idris Ọlanrewaju Okunẹyẹ, tawọn eeyan mọ si Bobrisky, ṣe fi awọn aga onike ṣetọrẹ fun ọgba ẹwọn Kirikiri, nibi to ti n ṣẹwọn lọwọ.
Dọsinni awọn aga onike funfun kan, eyi ti wọn kọ orukọ rẹ si lara, ni wọn ni Bobrisky paṣẹ ki wọn ko wọnu ọgba ẹwọn naa, o si fi ṣetọrẹ aanu, pe ki wọn ko o si aaye igbalejosi, kawọn alejo ti wọn n ṣabẹwo sawọn eeyan wọn lẹwọn le maa ri nnkan fi jokoo.
Lara ọkọọkan awọn aga ọhun ni wọn kọ akọle si bayii: “Fun ọgba ẹwọn Naijiria, lati ọwọ Idris Okunẹyẹ Bobrisky”.
Iṣẹlẹ yii ya ọpọ awọn ẹṣọ ọgba ẹwọn ọhun lẹnu, wọn si kan saara si ọkunrin naa, wọn ni onironu ẹda ni.
Bakan naa la gbọ pe awọn ẹlẹwọn ẹlẹgbẹ rẹ gboṣuba fun un, fun iwa ọlawọ rẹ lai ka ohun to n la kọja lasiko yii si.
Lori ẹrọ ayelujara, ọtọọtọ loju tawọn eeyan fi wo ohun ti Bobrisky ṣe yii. Nigba ti awọn mi-in n gboriyin fun un pe iwa to hu naa le jẹ ko ba aanu ati ojurere awọn alaṣẹ ọgba ẹwọn pade, ti wọn si n ṣadura fun un pe Ọlọrun yoo ko o yọ ninu adojukọ to n la kọja yii, sibẹ, niṣe lawọn mi-in n tẹmbẹlu ohun ti Bobrisky ṣe, wọn ni iwa naa ko yatọ si atẹyin-k’ọgbọn ijakumọ, to n nudi ko too ṣu, leyii to tumọ si pe ohun to yẹ ki ọkunrin naa ti ṣe pẹlu owo rẹ ṣaaju ki ẹsun ṣiṣe owo baṣubaṣu too ṣẹlẹ ni.
Tẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni adajọ la amẹwọn oṣu mẹfa. Ẹsun ṣiṣe owo Naira ilẹ wa baṣubaṣu ni wọn fi kan an