Tirela kọ lu kẹkẹ Maruwa ni Sango-Ọta, ẹni kan ku lẹsẹkẹsẹ, ọpọ ṣeṣe

Faith Adebọla

Ọkọ akẹru gbọgbọrọ kan ti ko mọlẹbi baale ile kan to doloogbe sinu ọfọ ati ibanujẹ laaarọ kutu ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, latari bi ọkọ ọhun ṣe lọọ fori sọ kẹkẹ Maruwa ati ọkọ akẹru mi-in to wa niwaju rẹ, ijamba naa si ṣeku pa ẹni kan to duro sẹgbẹẹ ọna, nigba ti eeyan mẹfa fara gbọgbẹ loriṣiiriṣii.

Nọmba to wa lara awọn ọkọ nla meji ọhun ni FST926YA ati GSW180XA nigba ti nọmba ara kẹkẹ Maruwa jẹ KLE76KT.

Alakooso eto iroyin fun ajọ alaabo oju popo, Federal Road Safety Corps, FRSC, ẹka ti ipinlẹ Ogun, Abilekọ Florence Okpe, ṣalaye pe nnkan bii aago meje kọja iṣẹju mẹwaa laaarọ ọjọ Aje, Mọnde, niṣẹlẹ naa waye.

O niṣe ni ọkọ ajagbe Howo kan n ba ere buruku bọ ni gẹrẹgẹrẹ ọna marosẹ to lọ si too-geeti Sango, nigba ti yoo si fi kan awọn ọkọ to wa niwaju rẹ, dẹrẹba tẹ bireeki, amọ ijanu naa daṣẹ silẹ, lo ba sẹri mọ Maruwa ati ọkọ mi-in.

Okpe ni lẹsẹkẹsẹ tawọn ẹṣọ Road Safety ti debi iṣẹlẹ naa ni wọn ti gbe awọn to fara pa lọ si ọsibitu Jẹnẹra Sango Ọta, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ, amọ loju-ẹsẹ ni ọkunrin to doloogbe ti ku, tawọn dokita si ti fidi iku rẹ mulẹ, awọn si ti yọnda oku rẹ fawọn mọlẹbi onitọhun.

Ọga agba ajọ Road Safety nipinlẹ Ogun, Anthony Uga, ti tun lo anfaani yii lati parọwa sawọn onimọto pe ki wọn maa ṣayẹwo ọkọ wọn laraarọ ki wọn too ṣina rẹ, ki wọn yẹra fun ere asapajade.

 

Leave a Reply