Wọn lawọn alapata kan n ta ẹran maaluu ti majele pa faraalu n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ṣe ni ibẹrubojo gbilẹ niluu Ilọrin ati gbogbo agbegbe rẹ lati ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, latari bi iroyin ṣe gba igboro pe awọn alapata kan n ta ẹran maaluu ti majele pa fun awọn araalu, leyii to lewu fun ilera wọn, ni ijọba Kwara ba lọọ ti ọja naa pa.

Ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Kwara Monitoring Group (KMG), lo kọkọ pe akiyesi ijọba si iṣẹlẹ naa, ti wọn si rọ gbogbo araalu lati takete si rira irufẹ ẹran bẹẹ nitori alaafia wọn, nitori pe wọn o mọ iru iku to pa awọn maaluu ọhun.

L’Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ ayika nipinlẹ naa lọọ ti ọja ti wọn ti n pa ẹran maaluu ọhun pa fun ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.

Akọwe agba ileeṣẹ naa, Dokita Abubakar Ayinla, sọ pe idi tawọn fi lọọ ti ọja naa pa ni lati le daabo bo araalu lori iṣẹlẹ maaluu ti wọn ni wọn jẹ majele ọhun. O ni l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹrin yii, ni ọja naa yoo jẹ ṣiṣi pada.

Lara awọn to lọọ ṣabẹwo si ọjọ ọhun ni Kọmiṣanna to n ri si ọrọ eto ọgbin ati idagbasoke igberiko, Arabinrin Toyọsi Thomas Adebayọ, Kọmisanna lẹka eto ilera, Dokita Amina Ahmed El-Imam, Akọwe ajọ to n daabo bo imọtoto ayika ni Kwara, Arabinrin Fọlọrunsọ Idayat, ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn sare lọ sinu ọja Mandate, nitori ki wọn ma baa ta ẹran awọn maaluu to ku ọhun fun araalu.

Ijọba ti rọ gbogbo araalu pe ki wọn maa foya rara, awọn ko ni i gba awọn alapata naa laaye lati tẹ ẹran ọhun sita.

Tẹ o ba gbagbe, lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, lawọn maaluu to le ni ogoji to jẹ ti awọn ontaja kan ti wọn n ta maaluu ninu ọja Mandate, Adewọle, niluu Ilọrin, ti i ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara, ku lojiji latari majele ti wọn jẹ.

ALAROYE gbọ pe ni kete tawọn maaluu ọhun n ku ni awọn alapata to n ta maaluu ọhun n du wọn lọrun, ti wọn si n gbe ẹran naa lọ sinu ọja lati lọọ ta fun araalu.

Leave a Reply