Eedi ree, baba atọmọ ku sinu ṣalanga nibi ti wọn ti fẹẹ yọ foonu

Adewale Adeoye

Baba agbalagba kan, Oloogbe Mallam Danjuma, ẹni ọgọta ọdun tawọn eeyan mọ si Black nigba aye rẹ, ọmọ rẹ, Oloogbe Ibrahim, ẹni ọdun marundinlogoji, ati ọrẹ ọmọ rẹ, Oloogbe Aminu, ẹni ọdun marundinlogoji, ni wọn padanu ẹmi wọn sinu ṣalanga kan lasiko tawọn mẹtẹẹta n gbiyanju lati yọ foonu igbalode kan to ja bọ sinu salanga lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, nipinlẹ Kano.

ALAROYE gbọ pe iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun waye lagbegbe Tsanyanwa, ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu yii.

Alukoro ileeṣẹ panapana ipinlẹ naa, Ọgbẹni Saminu Abdullah, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, sọ pe awọn alaṣẹ ileeṣẹ panapana agbegbe ibi ti iṣẹlẹ ọhun ti waye gba ipe pajawiri kan latọdọ awọn araalu pe awọn eeyan mẹrin kan wa ninu ṣalanga ti wọn ko le jade sita mọ, oju-ẹsẹ ni wọn si ti lọọ sibẹ lati doola ẹmi awọn eeyan naa.

Atẹjade kan ti wọn fi sita lori iṣẹlẹ ọhun lọ bayii pe, ‘‘Ni nnkan bii aago mọkanla aarọ ọjọ Aiku, ọsẹ yii ni awọn eeyan agbegbe Tsanyanwa, nipinlẹ Kano, pe, ohun ti wọn sọ ni pe foonu igbalode to jẹ ti Oloogbe Danjuma, ja bọ sinu ṣalanga lasiko to n ṣegbọnsẹ lọwọ, nibi to ti fẹẹ yọ ọ jade lo ti ko sinu rẹ, ọmọ rẹ, Oloogbe Ibrahim, fẹẹ yọ baba rẹ, loun naa ba ja bọ sinu ṣalanga naa, ko pẹ ni awọn meji kan ti wọn mọ si iṣẹlẹ ọhun ba gbiyanju lati yọ baba pẹlu ọmọ to wa ninu ṣalanga naa, ṣugbọn ṣe lawọn naa tun ja bọ sinu ṣalanga naa, nigba ta a maa fi debẹ, ẹpa ko boro mọ. A gbe awọn mẹrẹẹrin jade, ko daju pe awọn mẹta maa ye e, ṣugbọn ẹni kẹrin ṣi n ṣe daadaa. A ti fa gbogbo wọn le ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe naa lọwọ, awọn ọlọpaa ni wọn ko gbogbo wọn lọ sileewosan ijọba kan ti wọn n pe ni ‘Bichi Specialist Hospital’, to wa lagbegbe Tsanyanwa, nibi tawọn dokita ti fidi ẹ mulẹ pe mẹta ninu wọn ti ku, nigba ti ẹni kan yooku n gba itọju lọwọ nileewosan naa.

 

Leave a Reply