Eemọ ree o! Iyaale ile yii pokunso sinu yara ẹ ni Magboro

Adewale Adeoye

Titi di asiko ta a n koroyin yii jọ lọwọ lọrọ iyaale ile kan, Oloogbe Idowu Victoria, ẹni ọdun mọkandinlaaadọta to pokunso sinu ile rẹ to wa lagbegbe Magboro, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, ṣi n ya awọn araalu ọhun lẹnu gidi.

Ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, ni ọkan lara awọn ọmọ oloogbe naa ba oku iya rẹ to n mi diro-diro lori ikọ ninu yara ti wọn n gbe, lẹyin to pada de lati ṣọọṣi to lọ.

Loju-ẹsẹ lo ti figbe bọ’nu, tawọn araale ti wọn n gbe si waa wo ohun to n ṣẹlẹ si i.

Iyalẹnu nla gbaa niṣẹlẹ ọhun jẹ fawọn to ri oku oloogbe naa lori ikọ. Awọn araale naa ni wọn sare lọọ fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa Ibafo leti, tawọn yẹn fi wa sibẹ.

ALAROYE gbọ pe oloogbe naa ko ṣaisan, bẹẹ ki i ṣe pe o larun ọpọlọ ko too gbe igbesẹ buruku ọhun.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, S.P Ọmọlọla Odutọla, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe ọmọ oloogbe naa to de lati ṣọọṣi to lọ ni nnkan bii aago mẹta aabọ ọsan lo ba oku iya rẹ lori ikọ, lọmọ naa ba figbe bọnu, tawọn araale si waa ran an lọwọ. DPO teṣan Ibafo lo ran awọn ọmọọṣẹ rẹ lọ sibẹ, wọn ba oku oloogbe naa lori ikọ, wọn si re e bọ.

Alukoro ni, ‘Okun kan ni oloogbe fi so sori ikọ to ku si, ko sẹnikankan to mọ idi tabi ohun to fa a to fi gbe iru igbesẹ bẹẹ, a maa too bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ ọhun.

 

Leave a Reply