Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko bẹrẹ iwadii nipa agbofinro to gun araalu pa

Adewale Adeoye

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti bẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ bi Insipẹkitọ Taofeek, to jẹ ọlọpaa lagbegbe Ajah, nipinlẹ Eko, ṣe fọbẹ gun araalu kan, Oloogbe Anosikwe Patrick, pa lọjọ Abamẹta, Satide, ogunjọ, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii.

ALAROYE gbọ pe oloogbe ati ọlọpaa ọhun wa nile itaja igbalode kan ti wọn n pe ni Skymall, to wa lagbegbe Ajah, ọrọ ti ko to nnkan lo dija silẹ laarin ọlọpaa yii ati oloogbe naa, kawọn to wa nitosi si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, agbofinro ọhun ti fọbẹ aṣooro ọwọ rẹ gun oloogbe pa patapata. Iṣẹlẹ ọhun lo mu ki idarudapọ waye ninu ọgba ile itaja igbalode naa, tawọn araalu si n sa asala fun ẹmi wọn nitori ti wọn ko mọ ohun to le ṣẹlẹ lọjọ yii.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, S.P Benjamin Hundeyin, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fun akọroyin wa lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun yii, sọ pe awọn ti mu alakooso eto aabo ile itaja igbalode naa, awọn si ti n ṣewadii nipa iṣẹlẹ ọhun, ati pe ọdọ awọn ni Insipẹkitọ Taofeek to gun araalu ọhun pa wa bayii to n ran awọn lọwọ ninu iwadii awọn.

Alukoro ni ọga ọlọpaa patapata nipinlẹ Eko, C.P Adegoke Fayoade, ti paṣẹ pe ki awọn tuṣu desalẹ ikoko lori iṣẹlẹ naa.

Leave a Reply