Eeyan mẹẹẹdọgbọn jona ku lasiko ti mọto akero meji fori sọra wọn

Adewale Adeoye

Ero mẹẹẹdọgbọn to wa ninu mọto akero meji kan, Toyota ati Sienna, lo jona deeru lasiko ti mọto mejeeji gbana lẹyin ti wọn fori sọ ara wọn.

Iṣẹlẹ ibanujẹ ọhun waye lagbegbe Aloma, nijọba ibilẹ Ofu, nipinlẹ Kogi, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, laaarọ kutukutu. ALAROYE gbọ pe niwaju ileewe awọn olukọ kan ti wọn n pe ni, ‘Aloma Teachers College’, nijọba ibilẹ Ofu, ni iṣẹlẹ ọhun ti waye.

Awọn araalu tiṣẹlẹ ọhun ṣoju wọn ṣalaye pe ero mẹẹẹdọgbọn lo wa ninu mọto meji ọhun, iyẹn mọto Siena ati Toyota ti wọn fori sọ ara wọn, ere asapajude tawọn dẹrẹba ọkọ akero mejeeji ọhun n sa lo ṣokunfa iṣẹlẹ ọhun. Ọkan fẹẹ ya fun koto nla kan to wa laarin ọna, ṣugbọn ko tete mọ pe mọto mi-in n bọ niwaju rẹ, ati pe mọto tirela kan naa bajẹ sẹgbẹẹ ọna, eyi lo mu ki wọn kọ lu ara wọn.

Loju-ẹsẹ ti awọn mọto ọhun kọ lu ara wọn tan ni wọn ti gbana, tawọn ero mẹẹẹdọgbọn to wa ninu wọn ko si raaye jade titi ti wọn fi jona deeru.

Awọn araalu gbiyanju lati pana ọhun, ṣugbọn wọn ko ni irinṣẹ to to lati koju rẹ. Yatọ si mọto meji ọhun to gbina yii, tirela to bajẹ sẹgbẹẹ titi naa tun jona.

Awọn araalu ni ere asapajude ati titi ti ko daa lo ṣokunfa iṣẹlẹ laabi ọhun.

 

Leave a Reply