Ọpẹ o! Awọn ajinigbe ti yọnda pasitọ ijọ Ridiimu ti wọn ji gbe

Ọlawale Ajao, Ibadan

O daju pe orin ọpẹ lawọn ẹbi, ololufẹ ati ọpọ ọmọ ijọ Ridiimu lapapọ yoo maa kọ bayii pẹlu bi ọkan ninu awọn pasitọ ijọ naa,

Oluṣọ-agutan Olugbenga Ọlawore, ẹni ti awọn ajinigbe ji gbe, ṣe ti jade nibuba awọn olubi eeyan naa bayii.

Pasitọ Ọlawore, alakooso ṣọọṣi ti wọn n pe ni Heavens Gate Parish, Redeemed Christian Church of God, iyẹn, ẹka ijọ Ridiimu, to wa lọna Agbara si Lusada, nipinlẹ Ogun, ni wọn ji gbe pẹlu awọn ero mẹtala yooku ti wọn jọ wa ninu bọọsi kan naa.

Pasitọ yii lo padanu iya ẹ, to n jẹ Diakoni Deborah Ọlawore laipẹ yii, to si lọ siluu Ìpàpo, nipinlẹ Ọyọ, lati ṣeto bi ayẹyẹ ikẹyin iya rẹ naa ti wọn fi si Furaidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn (26), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ati Furaidee, ọjọ kẹta, oṣu Karun-un ọdun yii, yoo ṣe dun, ti yoo si larinrin, ko too kagbako awọn janduku agbebọn ti wọn ji i gbe lori irin-ajo rẹ pada siluu Eko.

Miliọnu mẹwaa Naira la gbọ pe awọn olubi eeyan naa n beere pe ki awọn ẹbi rẹ san fun awọn ki awọn too le fi i silẹ, ti ko si jọ pe ireti wa rara fun ojiṣẹ Ọlọrun naa lati bọ ninu igbekun awọn ajinigbe to ha si lati nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ Jimọ to ti ha sibuba wọn.

Ṣugbọn lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun (21), oṣu yii, niroyin ayọ gbode kan pe awọn agbofinro ti gba pasitọ naa silẹ lọwọ awọn ẹruuku.

Ṣaaju lọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Adebọla Hamzat, ti ṣeleri pe oun yoo gbe igbimọ atọpinpin kan dide laarin awọn ọlọpaa lati gba awọn arinrin-ajo naa silẹ lọwọ awọn ajinigbe.

Nirọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun (21), oṣu yii, ni Kọmiṣanna feto iroyin ninu ijọba Gomina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ, Ọmọọba Dọtun Oyelade, kede pe CP Hamzat, ti ṣaṣeyọri lori ileri to ṣe nipa ominira ojiṣẹ Ọlọrun naa.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Gbogbo bo ṣe n lọ la n beere lọwọ ọga agba awọn ọlọpaa nipa akitiyan wọn lati gba awọn ti wọn ji gbe silẹ, wọn si fi to ijọba leti pe awọn ti gba pasitọ ijọ Ridiimu yẹn silẹ pẹlu iranlọwọ awọn ikọ agbofinro ipinlẹ Ọyọ”.

O waa fi da awọn ara ipinlẹ Ọyọ loju lati fọkan balẹ nipa eto aabo, nitori awọn ọlọpaa atawọn agbofinro ipinlẹ naa kapa eto aabo ipinlẹ yii daadaa.

Ṣugbọn ohun ti kọmiṣanna naa ko mẹnu ba ninu atẹjade rẹ ọhun ni boya awọn agbofinro ri ẹlomi-in gba silẹ ninu awọn aririn-ajo yooku ti wọn ji gbe pẹlu pasitọ ijọ Ridiimu naa.

Leave a Reply