Faith Adebọla
Ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Eko ti ta ko ọrọ kan ti Ọga agba patapata fun ileeṣẹ ọlọpaa ilẹ wa, IGP Kayọde Ẹgbẹtokun, sọ laipẹ yii lori idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ, awọn aṣofin naa lawọn ko fara mọ erongba Ẹgbẹtokun, ati pe amọran rẹ ko le yanju iṣoro eto aabo to mẹhẹ lorileede yii.
Lasiko ijokoo wọn to waye ni gbọngan apero wọn l’Alausa, Ikẹja, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu Karun-un, ọdun yii, lawọn aṣofin naa ti fi aidunnu wọn han si Ẹgbẹtokun.
Ẹ oo ranti pe laipẹ yii ni Ẹgbẹtokun sọrọ ta ko idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ nibi apero ọlọjọ kan ti ileegbimọ aṣofin apapọ ṣeto rẹ niluu Abuja, nibẹ ni ọga yan-an yan-an fawọn ọlọpaa, ẹni ti igbakeji rẹ kan ṣoju fun, ti sọ pe Naijiria ko ti i goke agba to lati ni iru nnkan bẹẹ lasiko yii, kaka bẹẹ, niṣe ni kijọba da awọn ileeṣẹ agbofinro kan bii awọn ẹṣọ alaabo oju popo, Federal Road Safety Corps, FRSC ati Nigeria Security and Civil Defense Corps, iyẹn awọn Sifu Difẹnsi papọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa, lati ro awọn agbofinro lagbara. O ni idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ yoo mu kawọn oloṣelu maa ṣi agbara lo, bẹẹ ni ipenija gbigbe ẹru inawo, sisanwo-oṣu ati ipese nnkan eelo yoo ṣẹlẹ, gẹgẹ bo ṣe wi.
Amọ nigba to n sọrọ tako erongba yii, Olori awọn aṣofin ipinlẹ Eko, Ọnarebu Mudaṣiru Ajayi Ọbasa, sọ pe latigba ti wọn ti da ajọ Road Safety ati Sifu Difẹnsi silẹ, ko ti i ṣee ṣe fun wọn lati kapa ijamba ọkọ loju popo, bẹẹ lawọn ti wọn n bẹ agba epo ko rọlẹ, bawo ni wọn yoo ṣe waa ran eto aabo lọwọ bi wọn ba da wọn pọ mọ ileeṣẹ ọlọpaa.
Ọbasa ni: “Nipinlẹ Eko, a ni eto owo akanlo fun eto aabo (Security Trust Fund), eyi ti gbogbo ijọba kan to n de, latori Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, n lo lati ṣatilẹyin fawọn ọlọpaa Eko.
“Eyi fihan pe awọn aba ati erongba Ẹgbẹtokun ko muna doko, tori ko le yanju iṣoro, arun oju ni, ki i ṣe t’imu.
“Igbagbọ wa to fẹsẹ rinlẹ daadaa ni pe ta a ba le ṣedasilẹ ọlọpaa ipinlẹ, yoo ṣee ṣe lati kapa ipenija eto aabo, tabi ka din iṣoro naa ku gidigidi.”
Ọpọ awọn aṣofin Eko to sọrọ lori koko yii ni wọn kin Ọbasa lẹyin, ti wọn si ta ko Ẹgbẹtokun. Wọn tọka si apẹẹrẹ awọn orileede bii Amẹrika tabi United Kingdom, ti wọn ni ipele ati ẹka ileeṣẹ agbofinro, ti apapọ, ipinlẹ ati ibilẹ.
Lẹyin eyi ni awọn aṣofin Eko paṣẹ fun Akọwe wọn, Amofin Ọlalekan Ọnafẹkọ, lati kọwe erongba wọn si Ẹgbẹtokun ati ileegbimọ aṣofin apapọ l’Abuja.