Ọlawale Ajao, Ibadan
Ẹjọ kan ti itan ko ni i gbagbe bọrọ waye ni kootu Majisreeti Ibadan, lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹfa, oṣu karun-un, ọdun 2024 yii, nigba ti awọn baale ile meji kan fara han ni kootu ọhun nitori ti wọn ji burẹdi kọọkan mu.
Ọga agba ọlọpaa nipinlẹ Ọyọ, CP Adebọla Hamzat, lo pe wọn lẹjọ si kootu, o lawọn ọkunrin naa, Ibrahim Adeniyi, to jẹ ẹni ọdun mọkanlelogoji (41), ati Ebenezer Oluṣesi, ti oun ko ju ẹni ọdun mọkanlelọgbọn (31) lọ ni tiẹ, ji burẹdi nla kọọkan gbe.
Kọburu David Adepọju, ẹni to ṣoju CP Hamzat nile-ẹjọ, ṣalaye pe ẹka ileetaja igbalode kan to n jẹ Foodco, eyi to wa laduugbo Ring Road, lawọn olupẹjọ naa ti n ṣiṣẹ.
Ileeṣẹ yii lo n ṣe burẹdi Foodco, ti ọpọ eeyan fẹran. Burẹdi ọhun naa ni Ibrahim ati Ebenezer ji mu lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kejidinlọgbọn (28), oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii, ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ naa si fi fọlọpaa mu wọn, ti wọn si tori ẹ pe wọn lẹjọ si kootu.
Gẹgẹ b’ALAROYE ṣe gbọ, ẹẹdegbeje Naira (₦1,300) ni wọn n ta ẹyọ burẹdi ti wọn ni ọkọọkan awọn olujẹjọ naa ji, apapọ burẹdi ti awọn mejeeji si ji jẹ ẹgbẹrun meji ati ẹgbẹta Naira (₦2,600) niye.
O ni ọran ti wọn da lodì sofin ọdun 2000, eyi to ṣe iwa ọdaran leewọ, to si la ijiya lọ.
Nigba ti wọn ka ẹsun ọdaran ti wọn fi kan wọn si wọn leti lọkọọkan, awọn mejeeji sọ pe awọn ko jẹbi ẹsun naa.
Lẹyin naa ladajọ kootu ọhun, Onidaajọ Ọlabisi Ogunkanmi, gba beeli ọkọọkan wọn pẹlu ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (₦50,000)
O waa sun igbẹjọ naa si ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.