”Ẹ gba wa o! Awọn ọdọ tijọba ipinlẹ Eko da pada s’Ọṣun ti n ṣakoba fun wa o”

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Awọn olugbe ilu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun, ti kegbajare si Gomina Adeleke lati tete wa nnkan ṣe sọrọ awọn ọdọ ti wọn to irinwo, eyi ti wọn ni wọn fi bọọsi nla nla ru wa siluu naa lati ipinlẹ Eko.

Lopin ọsẹ to kọja ni iroyin jade pe ijọba ipinlẹ Eko ko awọn ọdọ naa ti wọn wa kaakiri agbegbe bii Lagos Island, Ajah ati bẹẹ bẹẹ lọ, lẹyin ti wọn ṣa wọn kaakiri tan ni wọn ko wọn sinu bọọsi, ti wọn si mori le ilu Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun.

A gbọ pe orita kaakiri ni wọn ja awọn eeyan naa si ninu ilu Ileṣa, awọn orita bii ojuọna Ileṣa si Akurẹ, Breweries, Ileṣa si Ì̀bòdì si Iginla, ọna Ọṣun Ankara, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Lẹyin iroyin yii ni Gomina Ademọla Adeleke sọ pe oun ti pe Gomina Eko, Babajide Sanwoolu, iyẹn si sọ pe oun ko mọ nnkan kan nipa bi wọn ṣe ko awọn eeyan naa pada si Ọṣun.

Ṣugbọn awọn olugbe ilu Ileṣa ti rawọ ẹbẹ si Adeleke, wọn ni ọrọ naa ki i ṣe eyi ti gomina le fi ọwọ yẹpẹrẹ mu, afi kijọba tete gbe igbesẹ kiakia lori ẹ.

Alagba Mustapha Ọlaoye to ba ALAROYE sọrọ ṣalaye pe pẹlu ipo ti eto aabo ilu Ileṣa wa tẹlẹ, inu aibalẹ aya lawọn araalu wa bayii, nitori ṣe lawọn ọdọ naa n rin kaakiri agboole.

O ṣalaye pe ibi ti ilẹ ba ṣu wọn si ni wọn n sun si, ṣe ni wọn si n tọrọ ounjẹ kaakiri lojoojumọ, nitori ko si iṣẹ kankan ti wọn n ṣe bayii.

O ni, ‘’Ijọba nilo lati ṣaanu wa n’Ileṣa o, ki wọn ko gbogbo awọn ọdọ yii pada soju kan, ki wọn ba wọn sọrọ lori iwa ọmọluabi, ki wọn si beere iṣẹ-ọwọ ti onikaluku wọn ba fẹẹ maa ṣe.

‘’Lẹyin eyi, kijọba da wọn lokoowo, ki wọn si ṣeto ilegbee fun wọn. Lai ṣe bẹẹ, iwa janduku ati oniruuru iwa palapala ni yoo gbìlẹ laarin wọn, ti awọn ọmọ ganfe to wa ni ilu Ileṣa tẹlẹ ba si darapọ mọ wọn, wahala nla ni o.

‘’Ṣe ni wọn n rin kaakiri oju popo bayii, ewu nla si ni eleyii jẹ fun wa, paapaa awọn ọmọ keekeeke ti wọn n lọ sileewe, ṣe la n tẹle wọn lọ sileewe bayii, ti a si tun n lọọ mu wọn lọsan-an’’

 

Leave a Reply