Wọn ti mu awọn akẹkọọ fasiti mẹjọ to n ṣẹgbẹ okunkun l’Ado-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti, ti kede pe ọwọ awọn ti tẹ eeyan mẹjọ ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun nileewe Yunifasiti ipinlẹ Ekiti.

Alukoro awọn ọlọpaa nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni  Sunday Abutu, ṣalaye pe sọ, o ni awọn ọdaran naa ti wọn wa lakata wọn ni olu ile iṣẹ wọn tio wa l’ọna Iyin-Ekiti, ni Ado-Ekiti ni wọn ti  f’ọrọ wa wọn lẹnu wo.

O ṣalaye pe sadeede lawọn ọlọpaa ẹka kogberegbe gba ipe pe awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kan ti wọn n pe ara wọn ni (Buccaneer) n da ọgba yunifasiti naa ru.

Ni kete ti wọn gba ipe yii ni wọn ko awọn ọlọpa kogberegbe lọ sinu ọgba yunifasiti naa, lasiko naa ni ọwọ awọn ọlọpaa tẹ eeyan mẹjọ, ti wọn jẹ ọmọ Yunifasiti ipinlẹ Ekiti.

Orukọ awọn ọdaran naa ti Abutu fi lede ni: Onifade Joshua Akinṣola, to wa ni ọdun kẹrin, ni ẹka eto ẹkọ Oṣelu (Political Science), Ọlatunde David, to wa ni ọdun kẹrin ni ẹka imọ ẹkọ Kọmputa (Computer Sciences), Ọmọboyewa Ọlabode, to wa ni ọdun kẹrin ni ẹka imọ ẹkọ oṣelu (Political Sciences)

Awọn yooku nii, Daniel Oluwagbenga, to wa ni ẹka eto ẹkọ iṣiro owo, Adeleke Tọlani, Andrew Ochuko, Bamiduro Ahmed Olawale ati Adelakun Ọmọniyi, to ti ṣetan ni yunifasiti naa lati ọdun 2023.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, lakooko ti wọn feẹ mu awọn ọdaran naa ni awọn kan lara wọn bẹrẹ si i yinbọn si ọkọ awọn ọlọpaa, ti wọn si fọ gilaasi ọkọ naa. Alukoro ni gbogbo eto n lọ lọwọ lati fi panpẹ ofin mu wọn, ati lati sa gbogbo agbara lati gba awọn ohun ija to wa lọwọ wọn.

Lara awọn ohun ija ti wọn gba lọwọ wọn ni fila alawọ yẹlo meji, ti wọn ya amin idanimọ Baccernia si, atawọn nnkan miiran.

Leave a Reply