Bo o lọ o yago lọrọ di lowurọ kutu ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii niluu Akurẹ, lagbegbe Ọba Adeṣhida, nipinlẹ Ondo, nigba tawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ati APC kọju ija buruku sira wọn.
ALAROYE gbọ pe eeyan meji ni ibọn ti ba bayii, ati pe ṣaaju asiko yii ni awọn eeyan kan ti ṣeku pa ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC kan ni Ọba Nla, niluu Akurẹ, iyẹn lọjọ Abamẹta, Satide. Ẹni ti wọn pa yii lo ṣokunfa wahala to tun bẹ silẹ laarin awọn janduku oloṣelu yii niluu Akurẹ ni Sannde.
Ọpọlọpọ eeyan ni wọn sọ pe wọn ti fara gba ninu ija buruku yii, bẹẹ ni wọn ba mọto jẹ, ti awọn mi-in si sa asala fun ẹmi wọn. Ba a ti ṣe n ko iroyin yii jọ, a gbọ pe ija naa ti tan ka de agbegbe kan ti wọn n pe ni Erakhale, ti ko si si onimọto kankan to fẹẹ lọ si agbegbe ọhun, paapaa oju ọna Ọba Adeṣhida.
Wọn lawọn tọọgi oloṣelu ti wọn n lera wọn kiri yii fẹẹ to aadọta, bẹẹ lẹnikan tiṣelẹ ọhun ṣoju ẹ sọ pe awọn ọlọpaa paapaa ti wọn wa nitosi iṣẹlẹ ọhun fẹsẹ fẹ ẹ ni, nigba ti wọn ri ohun ija oloro tawọn tọọgi oloṣelu ọhun n fi n ba ara wọn ja.