Obinrin to ti figba kan jẹ aṣoju orilẹ-ede Naijiria lorilẹ-ede Netherland yii sọ pe gbogbo awọn ohun ti ijọba Awolọwọ mu ni koko iṣẹ idagbasoke pata ni ko si fawọn eeyan lasiko yii, ati pe bi orilẹ-ede yii ṣe ri loni-in, o yatọ patapata si erongba Ọbafẹmi Awolọwọ.
Dosumu ni ọpọ nnkan ni inu Awolọwọ ko ni i dun si bayii, o ni, ṣe bi igbe aye awọn eeyan ṣe ri lasiko yii ni, abi bi awọn ohun amayedẹrun gbogbo ko ṣe si, ti eto iṣejọba paapaa ko dara to. O ni ẹkọ ọfẹ paapaa ko ṣe deede, bẹẹ gbogbo wa yii naa la gbadun eto ẹkọ-ọfẹ ti ijọba Awolọwọ ṣe, ati pe ayipada nla le de ba gbogbo ohun ta a ka silẹ yii, ti a ba ṣetan lati ṣe e lọna to yẹ.
Ninu ọrọ ẹ naa lo ti sọ pe lara awọn eeyan to gbiyanju lati ja fun ominira orilẹ-ede yii ni Ọbafemi n ṣe, ṣugbọn lọjọ ti a n ṣẹyẹ ominira Naijiria lọdun 1960, iwa buruku gbaa ni wọn hu si Ọbafẹmi, nitori ibi ti wọn fi aga ẹ si lọjọ naa ku diẹ kaato.
O ni, bo tilẹ jẹ pe oun ko ju ọmọ ọdun mọkanla lọ nigba yẹn, sibẹ, bi awọn obi oun ti ṣe n sọ ọ ninu ile, lẹyin ayẹyẹ ominira lọjọ naa fi han pe aaye awọn to ti ṣiwọ ninu iṣẹ ijọba ni wọn to baba oun si, ti iṣẹlẹ naa ko si dun mọ ẹbi atawọn eeyan ẹ ninu gẹgẹ bi olori ẹgbẹ alatako to wa. O ni, pẹlu iwa ti wọn hu yii, sibẹ, idunnu nla lo jẹ fun Ọbafẹmi pe Naijiria bọ lọwọ ijọba amunisin.
Tokunbọ Awolọwọ fi kun ọrọ ẹ pe, meloo gan-an la fẹẹ ka ninu ohun rere ti ọkunrin oloṣelu naa ṣe fun ilọsiwaju Naijiria. O ni iwe nla kan wa ti ọkunrin naa kọ, ṣugbọn ede to fi kọ ọ, oun nikan lo ye daadaa, akọle iwe naa si ni, ‘Fun igbe aye rere awọn eeyan’ (For the Good of the People). Ṣugbọn ede ti Awolọwọ fi k̀ọ ọ, oun nikan lo mọ itumọ ọrọ to kọ, ko si eyikeyii ninu awọn to n tẹle e to le tumọ ẹ.