Aderounmu Kazeem
Pẹlu bi awọn eeyan ilẹ America ṣe n mura lati gbọ ẹni to gbegba oroke ninu ibo to waye ni Tusidee, Ọjo Iṣẹgun, to kọja yii, Joe Biden tun ti jawe olubori ni ipinlẹ Pennsylvania bayii, ọkan lara awọn ibi pataki ti Donald Trump ti ri ibo to pọ daadaa tẹlẹ.
Bọrọ ṣe ri yii, ibo awọn aṣoju lawọn ipinlẹ ti Biden ti ni ti fẹẹ to ọtalelugba ati mẹwaa, eyi ti ṣe deede ibo ti oludibo gbọdọ ni lati jawe olubori.
Ni bayii, ibo ti Biden ti ni ti le ni ọtalelugba (264) latọwọ awọn aṣoju ni ipinlẹ kọọkan, nigba Trump ni tiẹ ni ibo to fẹẹ to okoolelugba (214).
Pennsylvania ti Joe Biden tun ti jawe olubori yii jẹ ọkan lara ibi ti ẹgbẹ oṣelu The Republican, ti Donald Trump dije labẹ asia ẹ ti lẹnu daadaa.
Ṣaaju asiko yii ni Trump ti n le iwaju ni Pennsylvania, ki Joe Biden too tun gba a mọ ọn lọwọ.
Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, ariwo ti Joe Biden atawọn alatilẹyin ẹ n pa ni pe o ṣe pataki ki wọn ka gbogbo ibo to ni i ṣe pẹlu eto idibo ọhun, nitori awọn ko fẹẹ gbọ iroyin to maa da nnkan ru fun awọn.