Bi awọn eeyan orile-ede yii ṣe n pariwo inira lori bi epo bẹntiroolu ṣe tun gbowo lori si i, ọkan ninu awọn minisita Buhari, Timipre Sylva, ti sọ pe ọrọ koronafairọọsi ati bi epo rọbi ṣe gbowo lori gan-an lo da wahala ọhun silẹ.
Ninu ọrọ ẹ pẹlu awọn oniroyin nile ijọba lẹyin ti minisita fọrọ epo yii ṣepade tan pẹlu Aarẹ Muhammadu Buhari lo sọ pe, bi ileeṣẹ apoogun, Pfizer, ṣe kede pe oun ti ri oogun to le kapa arun koronafairọọsi ni owo–epo rọbi ti lọ soke, ati pe oun naa lo fa a ti owo–ori epo bẹntiroolu naa ṣe wọn si i.
Sylva ni gbogbo igba ti epo rọbi ba ti n wọn lagbaaye ni yoo maa ni ipa lori iye ti wọn yoo maa ta jala epo bẹntiroolu, nitori latara epo rọbi naa ni wọn ti n yọ ọ.
Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni jala epo bẹntiroolu kuro ni naira mejidinlọgọjọ (N158), to si di ohun ti wọn n ta ni naira mejidinlaadọsan-an (N168) si aadọsan-an naira (N170) bayii.
Oro ijoba yii suwa, sugbon mo igbagbo wipe eniti olohun o lee mu koitida….. olohun yoo gba agbara lowo won…