Jide Alabi
Aarẹ orilẹ-ede Amẹrika, Donald Trump, ti kede pe oun loun wọle ninu idibo aarẹ to waye lọjọ kẹta, oṣu kọkanla, ọdun yii.
Lori ikanni abẹyẹfo ẹ lo ti sọ pe awọn ti wọn n pariwo kiri pe Joe Biden lo wọle, iroyin ayederu ni wọn n gbe ka. Aarẹ yii fi kun un pe, “Ki lo mu awọn oniroyin ayederu yii maa ro pe Joe Biden lo maa di aarẹ, ti wọn ko si fẹẹ kọbi ara si esi ibo tiwa rara. Awa naa n mura de wọn daadaa, bẹẹ lo baayan ninu jẹ, ohun ti wọn sọ ofin orile-ede Amẹrika da bayii nitori ibo 2020.
“Pupọ ninu awọn to jẹ olubẹwo nibi ti wọn ti n ka esi ibo ni wọn ko fun laaye rara, ti awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ‘The Democrats’ fi raaye tọwọ bọ esi ibo aimọye miliọnu lati fi ṣatilẹyin fun oludije wọn.”
Aarẹ Amẹrika yii ni ohun ti oun mọ daju ni pe awọn eeyan gidi nilẹ Amẹrika ko ni i maa woran ki ibo ti wọn lawọn kan fi ṣeru lati gbe Biden wọle dohun itẹwọgba rara, nitori pe gbogbo aye pata lo n wo ibi ti ọrọ ọhun yoo ja si.