Jide Alabi
Ile-ẹjọ gíga kan niluu Àkúrẹ́ ti ni ki wọn lọọ ju ọkunrin kan, Alọ Oluṣọla, ṣewọn gbere lori ẹsun pe o fipa ba ọmọ ẹ lo pọ.
Adajọ Samuel Bọla lo paṣẹ yii lẹyin ti wọn ti ro ẹjọ ọhun niwaju ẹ pe latigba ti ọmọ naa ti wa lọmọ ọdun mẹwaa ni baba ẹ ti n fipa ba a sun.
ALAROYE gbọ pe ọmọ yii ko ju ọmọ oṣu mẹfa lọ ti iya ẹ ti binu gbe e ju silẹ, to sì ba tiẹ lọ.
Ileewe awọn ọmọ yii laṣiiri ọrọ ọhun ti tu nigba ti ọmọ naa sọ pe o pẹ ti ẹnìkan ti n fipa ba oun lo pọ.
O ni baba oun gan-an lẹni ti oun n sọ, ati pe oun ko ju ọmọ ọdun mẹwaa lọ to ti n ki oun mọlẹ.
Ọmọ yii ni ti oun ba ti beere owo lọwọ baba oun, yala owo ileewe tabi awọn owo pẹẹpẹẹpẹ mi-in toun fẹẹ fi tọju ara oun, kinni ẹ lo maa n sare fa yọ soun, ti baba oun yoo sì fipa ba oun sun.
Ọga ileewe ti ọmọ yii n lọ lo fọrọ ọhun to awọn ọlọpaa leti, loju ẹsẹ ni wọn si ti gbe e lọ s’ile-ẹjọ lori ẹsun onikoko kan, bẹẹ loun paapaa ti sọ pe oun ko jẹbi.
Ni bayii, Adajọ Bọla Samuel ti sọ ọ ṣewọn gbere nitori ti ọkunrin naa ko ni ẹri kankan lati fi gbe ọrọ ẹ lẹsẹ pe oun kò jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.