Jide Alabi
Asiko yii ki i ṣe eyi to dara rara fun ọkan ninu awọn akọrin ilẹ wa, Topẹ Alabi, pelu bi ọkunrin kan, Ọgbẹni Mayegun Oyegoke, ṣe jade bayii, to ni oun ni baba Ayọmikun, akọbi Tọpẹ Alabi.
Akọroyin ori ẹrọ ayelujara kan ti wọn n pe ni gistlovers lo kọkọ gbe iroyin naa jade, nitori oun ni ọkunrin to n ta ọkọ ayọkẹlẹ yii pe, to si ṣalaye fun un pe oun loun bi akọbi ọmọ Tọpẹ Alabi to n jẹ Ayọmikun, ti Tọpẹ fi orukọ ọkọ rẹ kun, iyẹn Alabi, ti ọmọ naa fi n jẹ Ayọmikun Alabi.
Ọkunrin yii ni ohun to dun oun ju ninu ọrọ naa ni bi Tọpẹ ko ṣe gba oun laaye lati ri ọmọ yii, ti wọn si yi orukọ rẹ pada si Ayọmikun Alabi, dipo Tọpẹ Oyegoke ti oun sọ ọ.
Nigba ti ALAROYE lọ sori ikanni ọkunrin naa, fọto ọmọbinrin yii kun ori ibẹ, bẹẹ lo si maa n ki ọmọ yii lasiko to ba n sọjọọbi lori ikanni Instagraamu rẹ.
Ninu ọrọ kan to kọ nigba ti ọmọ yii ṣọjọọbi ni ọjọ keje, oṣu karun-un, ọdun 2018, o ni, ‘Ọla (iyẹn ọjọ keje, oṣu karun-un, 2018) ni yoo pe ogun ọdun geerege ti mo bi ọ. Ile igbẹbi CAC (CAC Merternity Home), to wa ni PWD, Oshodi, la bi ọ si, ayọ si kun inu mi gidigidi nitori pe iwọ ni akọbi mi nile aye. Mo si sọ ọ ni Mary Ayọmikun Oyegoke ni ile mi to wa ni Ṣomolu, lọjọ kẹrinla, oṣu karun-un, ọdun 1998. Ayọmikun, emi ni baba to bi ọ lọmọ, ti ko si si ẹnikẹni to le sọ pe oun loun bi ọ yatọ si mi. Mo ki ọ ku oriire ọjọọbi, akọbi mi, mo nifẹẹ rẹ, titi aye ni n oo si maa nifeẹ rẹ. Mo gbadura pe ki o ṣe aṣeyege laye, ọmọ mi obinrin daadaa.’’
Bi ọkunrin naa ṣe kọ ọ sori ikanni rẹ niyi, to si gbe aworan ọmọ yii sibẹ.
Gbogbo awọn to fesi si ọrọ yii lori ẹrọ ayelujara ni wọn n sọ pe iṣẹlẹ naa ki i ṣe tuntun, ati pe niṣe lo da bii pe Oyegoke feẹ ba olorin ẹmi yii lorukọ jẹ pẹlu ohun to gbe sita yii. Ohun ti awọn kan n beere ni pe nibo ni ọkunrin yii wa nigba ti ọmọ naa bẹrẹ ileewe alakọọbẹrẹ, titi to fi jade nileewe girama, to si fi wọ yunifasiti, to tun fi jade.
Obinrin kan to pe ara rẹ ni ade.ade sọ pe Tọpẹ ti sọ ninu ifọrọwerọ kan to ṣe pe loootọ loun ti bi ọmọ kan ki oun too pade Ọgbẹni Alabi ti oun fẹ bayii.
Ninu ọrọ ti ọmọ Tọpe ba iwe iroyin Punch sọ lo ti ṣalaye pe Sọji Alabi nikan loun mọ gẹgẹ bii baba oun. O ni ọrọ ọkunrin naa ko jọ oun loju nitori mama oun ti sọ fun oun nipa rẹ, ṣugbọn ẹni kan ṣoṣo ti oun mọ gẹgẹ bii baba oun ni Sọji Alabi ti mama oun ṣegbeyawo pẹlu rẹ ni bii ogun ọdun sẹyin, to si ti n tọju oun latigba naa wa.
Ayọmikun ni ko sigba kankan ti mama oun dina fun Ọgbẹni Oyegoke lati ri oun. O ni nigba ti oun wa lọmọ ọdun mẹẹẹdogun ni mama oun ti maa n sọ pe ki oun ba baba naa sọrọ.
ALAROYE kan si Ọgbẹni Oyegoke lati gbọ tẹnu rẹ, ṣugbọn titi ta a fi kọ iroyin yii tan, ọkunrin naa ko ti i fesi si atẹjiṣẹ ta a fi ranṣẹ si i.
Ni temi o soji alabi ni baba omo yen nitori ogbeni mayegun ki i se baba ti o ni Ife omo