Ọpẹ o! Wọn ti tu awọn ọmọleewe ti wọn ji ko ni Katsina silẹ

Aderounmu Kazeem

Lọwọ aṣalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ana ni deede aago mẹsan-an, ni ijọba ipinlẹ Katsina kede wi pe awọn ọmọleewe Government Science Secondary School ti wọn ji ko lọ niluu Kankara ti gba ominira.

Awọn akẹkọọ bii ọọdunrun ati mẹtalelọgbọn ni ijọba ọhun sọ pe wọn ti bọ lọwọ awọn eeyan to ji wọn gbe, ti wọn si ti gba itusilẹ bayii.

Tẹ ọ ba gbagbe, ọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja lawọn ajinigbe kọlu ileewe ọhun, ti wọn si ji ọpọlọpọ ọmọleewe ko, ninu eyi tawọn kan ti bọ mọ wọn lọwọ, ti awọn bii ọọdunrun ati mẹtalelọgbọn (333) si wa lakata awọn janduku ọhun ki wọn too ri wọn gba pada lana-an.

Ninu ọrọ ti akọwe ijọba ipinlẹ naa, Ọgbẹni Mustapha Mohammed Inuwa, fi sita lo ti fidi ọrọ ọhun mulẹ, bẹẹ lo sọ pe wọn ti ko awọn ọmọ naa lọ sile ijọba ipinlẹ Katsina, lati fa wọn le gomina lọwọ

 

 

Leave a Reply