Gomina Katsina ni, ‘Opurọ lawọn Boko Haram, awọn kọ lo ji ọmọleewe ko, bẹẹ la o san kọbọ’

Aderounmu Kazeem

Bo tilẹ jẹ pe ohun ti awọn Boko Haram sọ tẹlẹ ni pe awọn lawọn ji awọn ọmọleewe ọhun ko, ni Kankara, nipinlẹ Katisina, Gomina Bello Masari ti sọ pe, irọ ni wọn n pa, bẹẹ nijọba ko san kọbọ fawọn ti wọn ji wọn gbe gan-an.

Gomina Masari, sọ pe ẹgbẹ Miyyeti Allah, iyẹn awọn Fulani darandaran ni wọn ṣeto bi wọn ti ṣe ri awọn ọmọ ọhun gba, bẹẹ ni ko ni i ṣe rara pẹlu awọn Boko Haram ti wọn ko ara wọn jade nigba kan wi pe awọn lawọn ji awọn ọmọ ọhun ko.

Aṣalẹ ana ni gomina yii sọ pe awọn janduku adaluru ni wọn ji wọn gbe, ki i ṣe ẹgbẹ Boko Haram bi awọn eeyan ọhun ti kọkọ kede ẹ wi pe awọn lawọn ṣiṣẹ ibi ọhun.

O ni ni nnkan bi wakati meloo kan sẹyin lawọn eeyan to n ba awọn ajinigbe ọhun sọrọ gba awọn ọmọleewe tiye wọn jẹ ọọdunrun ati mẹrinlelogoji (344) yatọ si ọọdunrun ati mẹtalelọgbọn (333) ti wọn n gbe kiri tẹlẹ wi pe wọn sọnu nileewe Government Science Secondary School.

Gomina Masari ti sọ pe, “Igbesẹ ti wa lori bi awọn dokita wa yoo ṣe ṣayẹwo fun wọn loni-in Furaidee, nitori bi wọn ti ṣe lo ọjọ mẹfa ninu igbo lọdọ awọn to ji wọn gbe. A ṣetan lati paarọ aṣọ fun wọn, lẹyin naa la o fa wọn le awọn obi wọn lọwọ.”

Ninu alaye ti ọkan lara awọn oṣiṣẹ gomina ọhun ṣe lo ti sọ pe ilu kan to n jẹ Tsafe lẹgbẹẹ olu ilu ipinlẹ Zamfara, ni Gusau, ni wọn ti ri awọn ọmọ ọhun, ti wọn si ko wọn lọ sile ijọba nipinlẹ Katsina.

 

 

Leave a Reply