Faith Adebọla, Eko
Awọn ọmọọleewe ojilelọọọdunrun o din mẹfa ti wọn ṣẹṣẹ tu silẹ lahaamọ awọn afẹmiṣofo Boko Haram ti ni ounjẹ ẹẹkan ni wọn fawọn laarin ọjọ meji nigba tawọn fi wa lahaamọ.
Lori eto ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels kan ti wọn ti fọrọ wa awọn ọmọleewe naa lẹnu wo laaarọ ọjọ Ẹti, Furaidee yii, lawọn ọmọ naa ti ṣalaye inira ati ewu ti wọn la kọja nigba ti wọn fi wa nigbekun Boko Haram.
Wọn tun sọ pe nnkan naa buru gan-an, tori wọn ko jẹ kawọn kuro loju kan naa ti wọn ko awọn jọ si, tawọn ba fẹẹ yagbẹ, wọn maa ni kawọn yagbẹ soju kan naa nibẹ, kawọn da yẹẹpẹ bo o, to ba si di alẹ, oju kan yẹn naa lawọn maa sun si.
Awọn ọmọ naa ni ko sẹni to wẹ ninu awọn fun odidi ọjọ meje gbako tawọn fi wa nigbekun ọhun, ṣugbọn wọn maa n fawọn lomi mu, bo tilẹ jẹ pe omi naa ki i ṣe omi to mọ gaara.
Awọn akẹkọọ yii ni ibi gbalasa kan ni wọn ko awọn si, oorun pa boto sawọn lara.
Ni bayii, ijọba ipinlẹ Katsina ti paṣẹ pe ki wọn ko awọn ọmọ naa lọ sọsibitu fun ayẹwo ati itọju, ki amojuto le wa lori ilera wọn.
Oru Ọjọbọ, Tọsidee yii, ni wọn tu awọn ọmọleewe ijọba Kankara, nipinlẹ Katsina, tawọn Boko Haram ji gbe lọjọ Ẹti, ọjọ kọkanla, oṣu kejila yii, ninu ọgba ileewe wọn.