Ọlawale Ajao, Ibadan
Ni nnkan bii aago mẹfa irọlẹ ọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii niṣẹlẹ ọhun waye nigba ti awọn araadugbo ọhun kan ka ọmọọlọmọ mọ ọkunrin ti ẹnikẹni ko mọ orukọ rẹ yii lọwọ.
Meji ni wọn pe awọn afurasi ajinigbe ọhun, nigba ti akara wọn tu sepo lawọn mejeeji fẹsẹ fẹ ẹ, ṣugbọn ti ọwọ ba ọkan ninu wọn. Awọn eeyan ko si ṣe meni ṣe meji, niṣe ni wọn dana sun ọkunrin naa, to si jona gburugburu.
Olugbe agbegbe ọhun kan ṣalaye fakọroyin wa pe “Awọn ikọ Amọtẹkun wa lati gba ọkunrin yẹn silẹ, ṣugbọn awọn eeyan yii yari kanlẹ, wọn ni awọn ko ni i jẹ ko lọ laaye.
“Emi naa ko si nile lasiko to ṣẹlẹ, ṣugbọn wọn lọmọ ti wọn ji gbe yẹn ko le ju ọmọ ọdun mẹjọ lọ. Lẹgbẹẹ titi ni wọn dana sun eyi tọwọ tẹ ninu wọn si laduugbo Akoyọmọ, l’Amuloko.
Nigba to n ba akọroyin wa sọrọ lori iṣẹlẹ yii, SP Fadeyi ti i ṣe Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ yii rọ awọn eeyan lati maa fi iṣẹlẹ to ba ni i ṣe pẹlu eto aabo to awọn agbofinro leti, dipo ki wọn maa fiya jẹ awọn afurasi ọdaran lọwọ ara wọn.