Faith Adebọla
“Ọlọrun kọ lo jẹbi ohun to n ṣẹlẹ si wa lorileede yii, awa funra wa la jẹbi. Ko yẹ ki Naijiria wa nipo otoṣi, ko yẹ kọmọ Naijiria kan maa febi sun. Ti pe a wa niru ipo ta a wa lonii yii jẹ abajade ipinnu tawọn olori ati ọmọ-ẹyin ṣe. Adura mi ni pe k’Ọlọrun ṣe ọdun 2021 ni rere fun gbogbo wa, ṣugbọn ko le ṣẹlẹ bẹẹ ta a ko ba ṣiṣẹ lati jẹ ko ri bẹẹ.
“Ọdun yii kun fun ọpọlọpọ ipenija fun gbogbo aye, paapaa fun wa ni Naijiria. Latori aisi aabo, aabo to mẹhẹ, dori ọrọ-aje to dẹnu kọle, ti wahala arun COVID-19 tun waa fọba le e.
“Mo gbagbọ pe a gbọdọ ṣiṣẹ kara ba a ṣe n gbadura karakara, ki ọdun to n bọ, 2021, le ja si rere fun wa. Mo mọ pe ko kan le ṣadeede ja si rere o, a gbọdọ ṣiṣẹ tọ ọ ni.
“Ọlọrun kọ lo jẹbi ohun to n ṣẹlẹ si wa lorileede yii, awa ara awa la jẹbi. Ko yẹ ki Naijiria wa nipo otoṣi, ko si yẹ kọmọ Naijiria kan maa febi sun. Ti pe a wa niru ipo ta a wa lonii yii jẹ abajade ipinnu tawọn olori ati ọmọ-ẹyin ṣe. Adura mi ni pe k’Ọlọrun ṣe ọdun 2021 ni rere fun gbogbo wa, ṣugbọn ko le ṣẹlẹ bẹẹ ta a o ba ṣiṣẹ lati jẹ ko ri bẹẹ.
Aarẹ orileede yii nigba kan, Oloye Oluṣẹgun Arẹmu Ọbasanjọ, lo sọrọ yii ninu iṣẹ ikini fun ọdun tuntun to wọle de tan yii to fi lede nile rẹ l’Abẹokuta, ipinlẹ Ogun, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.
Ọrọ naa ko tan sibẹ o, Ọbasanjọ ni, “Igba ta a ba ṣe ohun to tọ nikan lo maa to o ri bẹẹ, a o ti i bẹrẹ si i ṣe ohun to tọ bayii. Ta a ba bẹrẹ si i ṣe ohun to yẹ ka ṣe, ọrọ-aje wa maa ri bo ṣe yẹ ko ri, tori mo mọ pe ki i ṣe Ọlọrun lo diidi ṣe ọrọ-aje wa pe ko bajẹ bo ṣe ri yii.”
Baba naa fi kun un pe awọn nnkan rere ko le ṣadeede ṣẹlẹ o. O ni, “Mo fẹran akọmọna ileeewe kan to ka pe: ‘Tẹpa mọṣẹ, ko o si gbadura.’ Koko ọrọ naa ni pe iṣẹ teeyan ba ṣe lo maa jẹ ki adura ti tọhun ba gba wa si imuṣẹ.’’
O ni Korona ati ọrọ aabo to mẹhẹ lorileede yii ti mu kawọn kan ku iku aitọjọ.
O pari ọrọ rẹ pe kawọn to n ṣakoso lọwọ bayii pinnu lati ṣe rere, ki wọn ṣapa lati yi nnkan pada si rere pẹlu adura, igba ọtun yoo wọle de.