Jide Alabi
Bi awuyewuye ti gba igboro kan pe Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu ti ko arun Koronafairọọsi, tawọn eeyan si n gbe e kiri ni Oluranlọwọ ẹ nipa eto iroyin, Tunde Rahman, ti bọ sita bayii lati sọ pe iroyin irọ lasan ni.
Ninu iroyin ọhun ti wọn n pin kiri ni wọn ti sọ pe orilẹ-ede France ni aisan ọhun de e mọlẹ si, ṣugbọn oluranlọwọ ẹ ti sọ pe ko ri bẹẹ rara, ilu London lo wa, ati pe aisan kankan ko ṣe e, ọkunrin oṣelu naa kan lọọ gba atẹgun nibẹ ni.
Tunde Rahman fi kun ọrọ ẹ pe o ti fẹẹ to igba mẹẹẹdogun ti Bọla Tinubu ti ṣayẹwo arun Koronafairọọsi yii, ṣugbọn ti ko si lara ẹ rara.
O ni, “Ni gbogbo igba ti Aṣiwaju Bọla Tinubu ba ti ri i pe oun ti ṣepade tabi wa laarin awọn eeyan to pọ lo maa n saaba ṣayẹwo ọhun, bo tilẹ jẹ pe ki i fi ibomu ẹ silẹ nigba kan.
“Ju gbogbo ẹ lọ, arun Koronafairọọsi ko kọ lu Bọla Tinubu o, awọn to n wi bẹẹ, iroyin ẹlẹjẹ ni wọn n gbe kiri. Bẹẹ ni ko si ni France, bi wọn ṣe n gbe e ka, ilu London ni baba wa, nibi to ti n gba atẹgun alaafia sara, ko sohun kan bayii to ṣe wọn.”