Adefunkẹ Adebiyi, Abẹ́òkúta
Titi digba ti wọn yoo fi pari iwadii nijọba ipinlẹ Ogun ni ki Kọmiṣanna feto ayika, Ọnarebu Abiọdun Abudu-Balogun, ẹni ti ọmọ ọdun mẹrindinlogun kan, Barakat Melojuẹkun, fẹsun kan pe o tẹ oun lọmu, o si fẹẹ ba oun ṣerekere, bẹẹ lo n pe ogede, to si fẹẹ ti oun wọ ileewẹ rẹ lọọ rọọkun nile.
Ninu atẹjade ti Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Tokunbọ Talabi, fi sita lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii, ti i ṣe ọjọ kẹta, oṣu kin -in-ni, ọdun 2021, lo ti sọ ọ di mimọ pe Abiọdun gbọdọ ko gbogbo dukia ijọba to wa lọwọ rẹ silẹ bo ṣe n lọ sile rẹ yii. Wọn ni gbogbo ẹ ni ko fa le ọga agba ni ileeṣẹ ayika lọ́wọ́
“Bo ṣe jẹ pe a ko sọ pe Ọnarebu Abiọdun ṣẹ ẹṣẹ yii, ti a si n ṣiṣẹ lori atẹjade to fi síta pe oun ko huwa naa, sibẹ, igbesẹ yii fi ìjọba Gomina Dapọ Abiọdun han gẹgẹ bii ijọba ti ko faaye gba ṣiṣe obinrin niṣekuṣe, to si koriira awọn ìwa ẹsẹ yooku to jẹ iwa ọdaran.
‘A ṣetan lati gbogun ti iwa irẹjẹ ati ijẹgaba lori ẹni, bi ẹnikẹni ba si ṣẹ, ijọba ṣetan lati da ṣeria to yẹ fun un lai wo iru ẹni to jẹ tabi ipo to wa”
Lori iṣẹlẹ yii, ijọba ipinlẹ Ogun fọkan araalu balẹ pe oun yoo wadii ẹ fínní-finni, gbogbo aye ni yoo si mọ bo ṣe jẹ gan-an.