Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Lopin ọsẹ to kọja yii ni fidio kan bẹrẹ si i lọ kiri lori ẹrọ ayelujura. Iya kan, Moronkeji Salami, ti wọn di ni bandeeji lori babatutu, ti oju-ọgbẹ oriṣiiriṣii si kun ara ẹ lo wa ninu fidio naa.
Awọn Fulani darandaran kan ni wọn ni wọn yinbọn mọ iya yii lagbegbe Ijẹbu-Oru, nipinlẹ Ogun. Ṣugbọn titi dasiko ta a n kọ iroyin yii, iya naa ko ti i gbadun, inu irora nla lo wa, ẹni ba si ri bi iya naa ṣe n japoro lọsibitu yoo mọ pe kinni naa ki i ṣe kekere rara.
Ọmọ iya yii to ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣẹ waye sọ pe mama oun lọ si oko rẹ ni, lọna Idofẹ, o kọju si Ijẹbu-Oru.
Ọmọ naa sọ pe nigba ti iya de agbegbe Quarry, lo ri awọn maaluu to pọ, nigba naa ni mama oun fẹẹ yi ori ọkọ pada ( Iya yii n wa mọto lọ funra rẹ ni)
Ṣugbọn bo ṣe fẹẹ yipada ni awọn Fulani bii mẹjọ yọ si i lati inu igbo, wọn si yinbọn mọ taya mẹrẹẹrin to wa lara mọto Moronkeji, lawọn iyẹn ba lọ silẹ.
Lẹyin eyi ni wọn yinbọn mọ iya funra ẹ lọwọ, ika atanpako ọwọ osi rẹ si ge danu loju-ẹsẹ, bẹẹ ni wọn yinbọn mọ ọn lẹnu, to si fọ gbogbo agbọn iya yii pẹkẹpẹkẹ, bẹẹ ni ọgbẹ oriṣiiriṣii si tun wa lara rẹ.
Bi eyi ṣe ṣẹlẹ ni obinrin naa pirọrọ bii ẹni pe oun ti ku, ọmọ rẹ sọ pe awọn Fulani naa n mi in wo nibi to gbori le niwaju ọkọ, wọn fẹẹ mọ boya o ti ku loootọ, iya naa si pirọrọ sibẹ, ko jẹ ki wọn mọ pe ẹmi ṣi wa lara oun.
Ohun ti Ọlọrun fi yọ ọ niyẹn gẹgẹ bi ọmọ rẹ naa ṣe ṣalaye.
Ileewosan meji ni wọn kọkọ gbe e lọ ti wọn ko gba a, iyẹn ni Orù ati Ṣagamu. Ọsibitu jẹnẹra ipinlẹ Eko ni wọn pada gbe e wa fun itọju. Beeyan ba si ri fidio mi-in to n ṣafihan ibi ti wọn ti n tọju iya naa, ti awọn dokita n fi irin ṣonṣo pẹlu owu nu ẹjẹ to n jade nibi ika iya yii to ti ge danu, aanu iya agba yii yoo ṣeeyan gidi. Niṣe lawọn dokita n sọ fun un pe ko ma wobẹ, ko gbe oju si apa ibomi-in bawọn ṣe n ṣatunṣe si ika ti ko ju gbungbu lọ mọ ọhun.
Ẹjẹ lo kun gbogbo ori bẹẹdi ti iya yii wa, nibi ti wọn ko owu ti wọn fi n nu un si, bẹẹ ni mama naa n ke bii arobo, nitori inira nla to n jẹ.
ALAROYE de ileewosan jẹnẹra to wa n’Ikẹja, ṣugbọn wọn ni wọn ti gbe mama naa kuro ni ẹka awọn ti ibọn ba ba (Surgical ward). A tun wa a lọ si ẹka mi-in to jẹ tawọn obinrin nikan ti iru ijamba yii ba kan, (Female surgical ward), awọn naa sọ pe ko si lọdọ awọn mọ. Ṣugbọn nọọsi kan sọ fun wa pe akọsilẹ iya to n jẹ Moronkeji Salami yii wa lọdọ awọn, bo tilẹ jẹ pe awọn ti taari rẹ kuro ni wọọdu naa lọ sibomi-in toun ko le sọ.
Ohun kan to daju bayii ni pe Abilekọ Moronkeji Salami ko ni ika atanpako osi mọ, apa kan isalẹ ẹnu rẹ si ti bajẹ latari ibọn to ba a nibẹ.
Boya ni oju apa le jọ oju ara fun mama to n lọ soko rẹ jẹẹjẹ naa mọ, to pade awọn ti wọn pa aye rẹ da si bi ko ṣe fẹ.
Ibeere tawọn araalu n beere pelu ipaya ni pe ‘Ta ni yoo gba wa lọwọ awọn Fulani darandaran yii.’